Democarcy Day: Àwọn ọ̀rọ̀ tí Bola Tinubu fi ránṣẹ́ lórí àyájọ́ ìjọba alágbádá rèé

Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Tinubu

Asíwájú Bola Ahmed Tinubu, to jẹ́ èèkàn nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC ti ní àwọn tó le sọ àwọn ènìyàn di òtòsì àti àláìmọ̀kan, ni àwọn ń bá figagbága.

Bí orílẹ̀-èdè Naijiria ṣe ń ṣe àyájọ́ ìṣèjọba àwa ara wa ni Asiwaju ń ké pe àwọn ọmọ Nàìjíríà láti dúrò tí ètò ìjọba àwa arawa wámúwámu.

Tinubu pe ipe yìí lọjọ́ Eti pẹ̀lú àfikún pé, ètò ìjọba àwa arawa, pẹ̀lú iṣèjọba rere a ma mú ojúùtú bá ìpèníjà tó le ṣúyọ.

Àwọn ìtàn mánigbàgbé tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, Bí wọ́n ṣe ya Sinima Ayinla Omowura rèé, BBC Yorùbá fọ̀rọ̀ wá àwọn òṣèré lẹ́nu wò

Ó ní bí ìdójúkọ ṣe tílẹ̀ pọ̀ tó, tó sì ń kojú olúkúlùkù, síbẹ̀ Nàìjíríà gbọdọ̀ dúró ti ètò ìjọba àwa ara tó múná dóko.

Gómínà ìpínlẹ̀ Eko nígbà kan rí tún rọ Nàìjíríà láti dìde lòdì sí òhunkóhun tó le yí omí àláfíà ètò ìjọba àwa arawa dànù.

Àkọlé fídíò, Tunde Bakare: Àjọjẹ kò dún bẹ́nìkan kò ní ló fa ìjà S Igboho,bẹ́ẹ̀ ìjọbati gbẹ́rù kọjá orí

Asiwaju rọ wọ́n láti díde lòdì sí ìwà ipá àti jàgídíjàgan àti gbogbo àwọn gbọ́yìsọ̀yí, tí wọ́n ń fi ọ̀rọ̀ ẹnu wọn dá wàhálà sílẹ̀ láàrín àwùjọ Nàìjíríà.

"Àwọn tí á n bá jà ni àwọn tó n sọ ènìyàn di alámọ̀kàn ati òtòsì. A ń ṣe àyájọ ọjọ́ ìṣèjọba àwa arawa kìí ṣe nítórí pé àti rìn jìnà nínú rẹ̀, bí kò ṣe pé kí a ní ìwúrí láti túbọ̀ tẹ̀síwájú.

Nàìjíria sì ni ọ̀nà tó jìn láti lọ, àt ibi gíga láti dé àti láti jọ jùmọ̀ ṣe òhun rere bí orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà èèyàn kan." gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Tinubu

Asiwaju ẹgbẹ́ òṣèlú APC náà rọ ọmọ Nàìjíríà láti ránti MKO Abiola, tó ìjáwé olúborí ni June 12, 1993 tí wan sì jí àṣeyọrí rẹ̀ mọ lọ́wọ́.

Ó ní "Abiola kò káárẹ̀, sùgbọ́n ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ kí gbogbo ènìyàn báa le jẹ àǹfàní ètò ìjọba àwa-arawa tí wọn gbà lọ́wọ́ rẹ̀."

Àkọlé fídíò, Tunde Gbadamosi: Kìí ṣe Tinubu ní ipò ààrẹ̀ tọ́ sí, ìgbà wo ní ìtan ajá ń kan lèmọ́mù?

Tinubu ni láísì ìrúbọ́ tí Abiola ṣe kò ni si àjọtọ̀ June 12 lónìí.

Asiwaju wa rọ gbogbo ọmọ Nàìjíríà láti ránti àwọn ẹlòmíràn tó ti rúbọ láti mú kí ìjọba àwa-arawa wáyé ni Nàìjíríà.

"Ọnà àtàta láti buyì fún ènìyàn kìí ṣe nípa pípé orukọ wọ́n nìkàn, bí kò ṣe nípa kíké pe ẹ̀mí wọ́n àti ìrétí wọ́n nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa.

"Láti dí onígbàgbọ́ nínú ìjọba àwa-arawa, a kọ́kọ́ gbọdọ jẹ́ ọmọ Nàìjíríà.