Osogbo JTF vs Youth Protest: Àwọn ẹbí Idris Ajibola bèrè fún ìwádìí tòótó lórí ikú ọmọ wọn
Mọlẹbi ọmọkunrin ti o padanu ẹmi rẹ ninu iṣẹlẹ tawọn agbofinro ti le awọn ọdọ kan sẹnu iku ti ba BBC Yoruba sọrọ.
Baba ọmọdekunrin naa arakunrin Kehinde Ajibola sọ pe ọmọ oun kii ṣe oni yahoo yahoo ati pe iwa aibọwọ fofin lawọn agbofinro to ṣeku pa ọmọ naa hu.
Idris Ajibola lorukọ ọmọdekunrin naa gẹgẹ bi baba rẹ ti ṣe sọ ti o si jẹ ọmọ ọdun mọkandinlogun.
- Njẹ́ o mọ̀ pé bíi ọdún 700 sẹ́yìn ni wọ́n ti ń bọ Osun-Osogbo? Mọ̀ síi nípa ìtàn ojúbọ̀ nàá
- Wo ọ̀rọ̀ Fani-Kayode sí akọ̀ròyìn "blog" tó ní lílù ìyàwó rẹ̀ bíi bàrà ló mú wọn túká
- Èèwọ̀! Ọmọ Yahoo fẹ́ pa ìyá rẹ̀ ṣ'owó l'Eko
- Pósí ní mo fi ṣe igbá ọṣẹ́ - Afurasí ọmọ ‘Yahoo’ kà fún EFCC
- Ẹ jọ̀ọ́, ẹ má jẹ́ kí ikú ọmọ mi lọ lásán - Ìyá Tiamiyu tí ọlọ́páà pa
- Adunni Oluwole, akọni obìnrin tó tako òmìnira Nàìjíríà, ó ní òyìnbó kò gbọ́dọ̀ lọ
Ọgbẹni Kehinde ṣapejuwe Idris gẹgẹ bi ọmọ ti ko laapọn.
''Emi o si nile mo jade mo lọ ra nkan ni. Saadede ni ipe wọle pe ọmọ mi ti ku''
Ọgbẹni Kehinde sọ pe Idris ati ọrẹ rẹ gbe ọkọ jade lati lọ ra nkan ti wọn yoo jẹ ni ''bawọn ọlọpaa ṣe le wọn titi de oju iku niyẹn''

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT/TWITTER/ NIYI DARAM/OTHERS
Nigba ti BBC beere nipa ọrọ tawọn eeyan n gbe kaakiri pe awọn ọmọ oni yahoo yahoo ni awọn agbofinro lawọn n le ọgbẹni Kehinde ni ọmọ oun kii ṣe oni yahoo yahoo.
''Rara o. Ko si ẹni tẹ le bi leere. Ko si ẹni tii ṣe yahoo ninu wọn.Awọn ọlọpaa kan fẹ fi iyẹn ṣe kini fun wọn ni''
''Iwa ti wọn n hu, iwa pe a ko ni ijọba nilu ni wọn hu. Mo fẹ ki ọmọ Naijiria gbe mi nija mo si fẹ ki ijọba fi ijiya to tọ jẹ wọn''
Ijọba ipinlẹ Osun ti ṣapejuwe iku ọmọkunrin gẹgẹ bi eleyi to bani ninu jẹ.
Gomina Adegboyega Oyetola si sọ pe awọn yoo ṣe ẹkunrẹrẹ iwadii lati tu aṣiri ohun to ṣẹlẹ si ọmọdekunrin naa.
Awọn mọlẹbi Idris sọ fun BBC pe awọn aṣoju lati ọdọ ijọba ti kan si awọn ṣugbọn awọn ko tii ri ẹnikankan lati ọdọ awọn ọlọpaa.
Isẹlẹ iku awọn ọdọ lati ọwọ awọn agbofinro paapa awọn SARS jẹ nkan ti awọn eeyan Naijiria n bẹnu atẹ lu ijọba si.
Lọpọ igba awọn agbofinro wọnyi a maa fi tipa mu awọn ti wọn ba fura si ti awọn mii a si ma padanu ẹmi wọn lọwọ awọn agbofinro yi.
Ohun táa mọ̀ nípa ìfẹ̀hónúhàn Osogbo tí ikọ̀ SARS JTF lé afurasí "Yahoo Boy" dójú ikú
Alukoro fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọsun, Yemisi Opalola sọ fun BBC pe iwadii ṣi n lọ lati mọ ẹka ileeṣẹ alaabo to wa nidii iṣẹlẹ to mu ẹmi ẹnikan lọ nilu Osogbo.
Ọjọ Iṣẹgun ni iṣẹlẹ naa waye lasiko ti awọn oṣiṣẹ alaabo le awọn ọdọmọkunrin kan ti wọn pe ni afurasi ọmọ 'yahoo-yahoo', titi de oju iku.
Iroyin to n lọ ni pe awọn ọlọpaa lo fa sababi iṣẹlẹ.

Oríṣun àwòrán, NIGERIA POLICE
Ṣugbọn Opalola sọ pe awọn ọmọ ikọ alaabo to jẹ akojọpọ awọn ọmọ ileeṣẹ ologun, ọlọpaa, oṣiṣẹ ajọ civil defence, ati awọn to n risi iwọle-wọde, ti ijọba Ọṣun kojọ fun aabo, lo fa sababi ọrọ.
O ṣalaye pe gbogbo igbiyanju ọlọpaa lati ran pese iranwọ lori iṣẹlẹ naa lo foriṣanpọn, nitori pe okuta ni awọn araalu n sọ lu awọn ọlọpaa.
- 'Àwọn SARS ló yìnbọn pa ìyá mi'
- Mi ò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí ẹ fi kàn mí pé mo ya "Blue Film" nínú igbó Osun Osogbo - Jolaosho TBlak
- Kíni iyatọ tó wà láàrin FSARS àti SARS?
- Kolade Johnson; Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní ọwọ́ ti tẹ àwọn afurasí ọlọ́pàá tó ṣekúpaá
- Ayédèrú Lọ́yà tó ń díbọ̀n gbowó lọ́wọ́ aráàlú bọ́ sí gbaga ọlọ́pàá
- Ìsìpẹ́kítọ̀ d'àwátì, jàndùkú fara gbọta nínú ìjà ọlọ́pàá ati aráàlú ní Ogun
Ijamba naa mu ki awọn ọdọ kan ṣe iwọde lẹyin iṣẹlẹ naa, ti wọn si ba awọn nkan jẹ laarin ilu.
Olugbe ilu Osogbo kan to ba BBC sọrọ lori iṣẹlẹ naa sọ pe, ile itaja nla kan to wa ni aarin igboro ilu Osogbo ni awọn ọmọkunrin naa ti lọ ra nkan, lati ibẹ si ni awọn ọlọpaa naa ti n fi ọkọ le ọkọ wọn.
"Wọn le wọn titi kuro laarin igboro, titi wọn fi de ọna kan ti eeero ko fi bẹ ẹ pọ si lọna ẹyin odi ilu."
Awọn iroyin kan tilẹ n sọ lori ayelujara pe ọkọ baba ikan lara awsn ọdọmọkunrin naa ni wọn wa ninu rẹ, tako "ẹsun ti wọn fi kan wọn pe ọmọ yahoo-yahoo ni wọn.
Awọn ti ọrọ naa ṣoju wọn ni awọn ọdọ naa ba ọkọ awọn ẹṣọ alaabo JTF jẹ patapata ni agbegbe Alekuwodo, ni ilu Osogbo.
Iroyin sọ pe ẹnikan lara awọn ọmọkunrin naa ku, ti awọn yooku si farapa, lasiko ti ọkọ wọn kọlu opo ina kan, to si takiti.

Oríṣun àwòrán, TWITTER
Alukoro ọlọpaa ṣalaye pe awọn to ṣe iwọde ko jẹ ki awọn ọlọpaa de ayika ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye rara, lati doola ẹmi awọn ọmọkunrin naa.
"Iwadii ṣi n lọ lori iṣẹlẹ naa, a si ti da ọlọpaa si igboro lati le dkun wahala to ba fẹ ẹ waye.
A si ti ko ọlọ́pàá ranṣẹ síbi tí iṣẹlẹ naa ti ń waye lati jẹ ki alaafia jọba padà sibẹ."
Lori ibeere pe nibo ni oku ọmọkunrin naa wa ati awọn to farapa, Opalola sọ pe fun'ra awọn eeyan naa lo gbe wọn, nitori pe wọn o jẹ ki ọlọpaa ran wọn lọwọ.















