Seyi Makinde fún àwọn tó ń tajà lẹ́gbẹ́ títì l'Oyo ní gbèdéke ọjọ́ méje láti wábigbà

Oríṣun àwòrán, Twitter/oyo affairs
Ijọba ipinlẹ Ọyọ ti fun awọn to n taja lẹgbẹ titi lati wa 'bi gba ki wọn to fi imu ko ata ofin.
Kọmiṣọna f'ọrọ ayika ati amojuto ohun alumọni omi, Amofin Idowu Oyeleke lo sọ bẹẹ lasiko to fi n kopa lori eto ori redio kan niluu Ibadan.
Amofin Oyeleke ni ko ni saye fun tita ọja lawọn ọna ti ko ba igba mu mọ ni ipinlẹ Ọyọ paapa julọ tita ọja lẹgbẹ popo.
O ni awọn ti pe gbogbo awọn aṣiwaju awọn ọlọja lati fi ọrọ yii to wọn leti silẹ.
O ni lootọ awọn ọlọja kan ti kọlu awọn oṣiṣẹ ijọba to mu itọni ati igbaniniyanju lori ewu to wa ninu ka maa ta ọja loju popo eleyi to ni o ku diẹ kaa to gidigidi.
Tita ọja lẹgbẹ titi jẹ ọna itaja kan ti awọn ontaja ni ilu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ atawọn ilu miran fi n wa ọna ijẹ imu.









