Precious Chikwendu àti Femi Fani-Kayode gba ayélujára kan lórí gbọ́yìsọ̀yì pé tírélà gba àárín wọn

Femi Fani Kayode ati iyawo rẹ

Oríṣun àwòrán, INSTAGRAM/@REAL_FFK

Iroyin kan to n fẹ lẹlẹ kiri lorii pe tirela ti gba aarin Femi Fani Kayode ati iyawo rẹ, Precious Chikwendu eyi ti akọroyin aladani (blogger) kan gbe sita ti mu ko gba ikilọ to le latọdọ awọn mejeji.

Fani Kayode to ti figba kan jẹ minisita eto irina ofurufu lorilẹede Naijiria fesi si iroyin to n ja rayin-rayin kaakiri yii pe oun ati iyawo oun ti tuka tori ọrọ ifiyajẹni labẹle.

Ninu lẹta kan ti awọn agbẹjọro fi ranṣẹ si oniroyin ọlọdani yii ni BBC Yoruba ti ri i ti o jẹ jade pe, Fani Kayode sọ pe akọroyin ọhun n ba oun lorukọ jẹ pẹlu iru iroyin to kọ jade lọjọ kẹrindinlogun oṣu kẹsan, ọdun 2020.

"Iroyin naa n fi onibara wa han gẹgẹ bi alagabagebe, ẹni to n na iyawo ẹ, o tun sọ pe eeyan buruku ati afipa muni ni. Bakan naa o sọ pe aridaju pe oun ni baba awọn ọmọ ibẹta rẹ lọ́, gbogbo eyi da lorii idi ti iroyin rẹ ko fihan faraye lati sọ pe ootọ ni". Eyi wa lara ọrọ inu lẹta naa.

Àkọlé fídíò, 'Ọ̀nà àtijẹ kan ṣoṣo táa ní ni Màálù àwọn Fúlàní ti bàjẹ́'

Ki gan ni akọroyin ọlọdani naa kọ?

Ẹni to ni oju opo iroyin naa, Dimokokorkus kọ iroyin jade pe minisita tẹlẹ yii ati iyawo rẹ Precious ti tuka. O tẹsiwaju lati sọ pe labẹle naa lawọn ti gbọ iroyin pe nitori iwa ipa ati ifiyajẹni labẹle lo fa ituka igbeyawo wọn.

Lara ohun ti akọroyin naa tun kọ ni pe Precious kó jade nilee Femi Fani Kayode ni nkan bii oṣu mẹrin sẹyin lai ko awọn ọmọ mẹrin to bi fun un dani torii pe Kayode ni oun ko gbudọ ko firii rẹ ni tosi ile.

Bakan naa, iroyin ọhun sọ pe Fani Kayode ti gba ẹbun ọkọ to fun un atawọn nkan mii to ra fun un lasiko ti wọn jọ wa papọ. Iroyin naa tun sọ pe ọpọlọpọ igba ni Fani Kayode ko iya fun iyawo rẹ Precious koda o ni lilu bii bara waye nigba to wa ninu oyun awọn ibẹta.

Àkọlé fídíò, 'Búrẹ́dì tí wọn ó fi jẹ ẹ̀wà ni wọ́n lọ rà ni wọ́n pàdé ikú gbígbóná'

Ohun taa mọ nipa ituka igbeyawo wọn

Awọn agbẹjọro ọhun kọ lẹta pe Fani Kayode ni irọ gbogbo ni ọrọ to n fo kiri yii ko si si otitọ kankan nibẹ.

Fani Kayode nipe lori iroyin yii nikan, oun ti gba ọpọlọpọ ipe ori foonu lati kaakiri agbaye ti iroyin naa si ti ṣakoba fun oun.

Lẹta naa sọ pe o ti ṣe tan lati pa iroyin naa ti bi akọroyin ọhun ba ṣe atẹjade pe oun ti ko ọ̀rọ̀ oun jẹ pada lorii gbogbo ẹsun ti wọn lọ mọ Fani Kayode lẹsẹ loju opo iroyin rẹ ti wọn ti gbe iroyin ọhun sita gangan ko si lọ tọrọ aforiji lorii iwe iroyin Naijiria meji ati pe ko wa ba wọn duna dura lati san biliọnu meji naira owo gba ma binu laarin ọjọ mẹrinla pere bi bẹẹ kọ, ọrọ yii yoo kọri sile ẹjọ.

Ẹwẹ, Fani Kayode ko fi tara tara jade lati wa sọ boya bẹẹni tabi bẹẹkọ ni pe o kọ iyawo rẹ, Precious bẹẹ si ni Precious naa ko jade lati ṣe bakan naa.

Ṣugbọn loju opo Instagram Precious to n jẹ Snowwhiteey, ko si aworan Fani Kayode kankan nibẹ lasiko ti a ko iroyin yii jọ.

Precious Chikwendu jẹ oṣere ati arinrinoge tẹlẹri.