Self-certification form: Lẹ́yìn tí ìjọba Nàìjíríà pahùndà lóríi fọ́ọ̀mù tuntun, wo àwọn tọ́rọ̀ kàn

Buhari ati fọọmu naa

Oríṣun àwòrán, Twitter/government of nigeria

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ajọ agbowoori lorilẹede Naijiria, FIRS ti gbe alaye kalẹ lori bi ọrọ eto iforukọsilẹ fun awọn to ba ni aṣuwọn ifowopamọsi lorilẹede Naijiria.

Lẹyin to ti kọkọ kede pe gbogbo awọn to ba ni akanti ifowopamọsi ni ko lọ gba fọọmu naa, ijọba apapọ jade laarọ ọjọ Ẹti pe oun ko ọrọ naa jẹ ati pe ajọ agbowoori FIRS yoo kede awọn tọrọ naa yoo kan laipẹ.

Àkọlé fídíò, Wo ìdílé tí ìyá àti gbogbo ọmọ kara bọ iṣẹ́ ṣíṣe epo tà

Nigba ti ajọ agbowoori lorilẹ€de Naijiria, FIRS yoo fi jade pẹlu awọn ti ọrọ naa yoo kan, alaye wọn niyi:

Wo bi o ṣe lee gba fọọmu naa

ẹda fọọmu naa

Gẹgẹ bi ajọ FIRS ṣe sọ, kii ṣe gbogbo eeyan ni gbigba fọọmu yii tabi fifi ọwọ si fọọmu yii kan.

Ajọ naa ṣalaye pe awọn eeyan lee gba fọọmu yii lawọn banki ti wọn ba n lo.

Bakan naa lo ni wọn tun lee lọ si oju opo ayelujara ajọ FIRS lati tẹẹ jade nibẹ.

Bawo ni oju fọọmu naa ṣe ri?

ẹda fọọmu naa

Bi fọọmu iforukọsilẹ awọn iforukọsilẹ tuntun fawọn to ni aṣuwọn ifowopamọsi lorilẹede Naijiria ṣe ri ree.

Irufẹ meji ni fọọmu yii to wa. Ọkan wa fun awọn aladani, omiran si wa fun awọn onileeṣẹ.

Ipele mẹta ni tawọn aladani pin si.

ẹda fọọmu naa

Abalaakọkọ ni yoo maa bere awọn iroyin to ba yẹ nipa ẹni to ni aṣuwọn ifowopamọ si naa atawọn iroyin miran to jẹ mọ ọrọ owo ori rẹ.

Abala keji yoo beere iroyin nipa ibi ti ẹni to ni aṣuwọn ifowopamọsi naa n gbe fun anfani owo ori sisan pẹlu nọmba idanimọ fun owo ori sisan iru ẹni bẹẹ, iyẹn, Tax Identification Number, TIN

Abala kẹta yoo rọ eeyan to ni aṣuwọn naa lati jẹri si pe otitọ ni gbogbo awọn iroyin ti o ti fi silẹ lawọn abala akọkọ ati ikeji fọọmu iwe ẹri aṣuwọn banki naa.

Abala marun ni fọọmu to wa fawọn onileeṣẹ pin si:

ẹda fọọmu naa

Abala akọkọ: iroyin nipa ẹni to ni aṣuwọn naa eyi ti yoo ṣe afihan orukọ ileeṣẹ naa, ẹka ileeṣẹ naa, orilẹede ti wọn ti fi orukọ rẹ sọlẹ si labẹ ofin pẹlu adirẹsi fiweranṣẹ wọn.

Abala keji: ileeṣẹ naa yoo sọ irufẹ aṣuwọn banki tabi irufẹ ileeṣẹ iṣuna ti wọn n lo. (Fun apẹrẹ Investment Entity, Depository Institution, Custodial Institution or specified Insurance Company)

Abala kẹta: Ẹni to ni ileeṣẹ naa tabi ẹni to n ṣe akoso ileeṣẹ bẹẹ.

Abala kẹrin: ileeṣẹ to ni aṣuwọn naa gbọdọ sọ ibi to fikalẹ si to ti n san owo ori ati nọmba to fi n san owo ori, TIN.

Abala karun un:ileeṣẹ to ni aṣuwọn naa yoo jẹri si pe otitọ ni gbogbo awọn iroyin ti o ti fi silẹ lawọn abala akọkọ ati ikeji fọọmu iwe ẹri aṣuwọn banki naa.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Ìjọba àpapọ̀ gbá rìfáàsì lóríi fọ́ọ̀mù nípa akáǹtì rẹ ní báńkì

Aarẹ Buhari

Oríṣun àwòrán, TWITTER/@BASHIRAHMAAD

Ijọba apapọ ti tọrọ aforiji fun atẹjade to fi sita nipa fọọmu iforukọsilẹ fun awọn to ni aṣuwọn ifowopamọsi ni banki lọjọ Iṣẹgun.

Ijọba apapọ ṣalaye loju opo Twitter rẹ ni Ọjọ Ẹti pe aṣiṣe nla gbaa ni atẹjade naa.

O wa fi kun un pe ajọ agbowoori lorilẹede Naijiria, FIRS yoo maa gbe alaye to kunna jade lori rẹ laipẹ.

Ijọba apapọ tun ṣalaye pe nigba ti eto iforukọsilẹ naa ba bẹrẹ o loju awọn eeyan ti yoo kan.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Wo nkan tó yẹ́ kí o mọ̀ nípa òfin tuntun tí ìjọba Nàìjírià gbé síta nípa akáǹtì rẹ̀ ní báńkì

Ijọba orilẹ-ede Naijiria ti kede pe ki gbogbo ọmọ Naijiria to ni asunwọn owo nile ifowopamọ, ileeṣẹ adojutofo, ati awọn ileeṣẹ miran to n mojuto ọrọ owó, lọ gba fọọmu ti yoo mu ki wọn o fi aridaju han pe awọn lo ni awọn apo asunwọn naa.

Ọjọbọ ni ijọba kede aṣẹ tuntun yii, loju opo ayelujara Twitter rẹ, pe fọọmu naa ti wọn pe ni 'self-certification' ṣe pataki, fun iranlọwọ awọn ileeṣẹ to wa fun eto ẹnawo lati le tẹle awọn ilana to yẹ lori ofin ti ijọba fi sita loti ọrọ owo ori lọdun 2019.

Àkọlé fídíò, 'Ọ̀nà àtijẹ kan ṣoṣo táa ní ni Màálù àwọn Fúlàní ti bàjẹ́'

Ipele mẹta ni ilana tuntun yii pin si

Form of entity (eyi wa fun awọn ileeṣẹ)

For controlling Person (eyi wa fun awọn eeyan to ba ni aṣẹ lori asunwọn ẹlomiran)

Form for individual (eyi wa fun ẹni kọọkan to ni apo asunwọn ni banki)

Ijọba sọ pe ẹnikẹni to ba kuna lati tẹle ilana yii yoo jẹ iya to ts labẹ ofin, debi i pe o le padanu owo rẹ to wa ni ile ifowopamọ, tabi ko ma le lo apo asunwọn naa mọ.

Gbogbo ile ifowopamọ, ileeṣẹ adojutofo ati awọn miran ti o ba ni asunwọn si ni wa a ti gba fọọmu naa, ti o si gbọdọ ṣe akọsilẹ rẹ.

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

Skip X post, 4

End of X post, 4

Skip X post, 5

End of X post, 5

Ikede yii ti n fa ariwisi ati ikunsinu laarin awọn ọmọ Naijiria kan, paapa lori ayelujara.

Skip X post, 6
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 6

Skip X post, 7

End of X post, 7

Skip X post, 8

End of X post, 8