June12 Protest: Ọlọ́pàá ní kí aráàlú jòkó sílé wọn, tí aráàlú sì takú pé ẹ̀tọ́ àwọn ni láti wọ́de

Oríṣun àwòrán, Omoyele Sowore
Ọlọ́pàá ní kí aráàlú jòkó sílé yín, tí aráàlú sì takú pé ẹ̀tọ́ àwọn ni láti wọ́de
Ó ṣeṣé kí ìdojúkọ wà láàrín àwọn ẹgbẹ́ ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn gbogbo àti àwọn ọlọ́paàá, bí wọ́n ṣe ń pinnu lati se ìwọ́de fún ''June 12" jákèjádò àwọn ìpínlẹ̀ àti lókè òkun lónìí.
Ìwọ́de yìí ni wọ́n ń pinnu láti fi ṣe ayẹyẹ to n sami ọjọ ìṣẹjọba àwa ara wa to ko loni ni Naijiria.
Ọ̀pọ̀ àwọn ìwé pélébé ni wọn ti n pín ká lóri àyélujára àti àwọn òpó ìkànsíraẹni gbogbo lọ́jọ́ Eti tí wọ́n sì pín nilu Eko, Gombe Calabar, Yola Bauchi, Abeokuta, Yenagoa, Port Harcourt, Ilorin, Enugu, Akure, Yobe, àti Zaria ti ìwọ́de náà yóò ti wáyé.
Àwọn ìtàn mánigbàgbé tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Kókó ọ̀rọ̀ tí ààrẹ Buhari báwọn ọmọ Náíjíríà sọ ní àyájọ́ June 12
- Wo ipa mánigbàgbé táwọn ààrẹ ní sáà ìjọba alágbádá kẹ́rin ṣe
- Wo àwọn ààrẹ alágbádá tó ti jẹ ní Nàìjíríà láti 1960 di àkókò yìí
- MKO Abiola, iṣẹ́ aṣẹ́gità ló fi bẹ̀rẹ̀ okoòwò
- Ìjà Awolowo, Akintola àti ogun 'Wẹtiẹ', ẹ̀kọ́ wo ló kọ́ wa?
- Wo ìṣẹ̀lẹ̀ márùn-ún tí kò bá pín Nàíjíríà sí yẹ́lẹ-yẹ̀lẹ
- Taiwo Akinkunmi, ọmọ Ibadan tó ya àsìá Naijiria
- Alimotu Pelewura, Ìyálọ́jà akọ́kọ́ l’Eko tó mi amúnisìn àti ìjọba tìtì
- Ìdílé márùn-ún tó gbajúmọ̀ fún òwò ẹrú nílẹ̀ Yorùbá
- Ogun Àgbẹ́kọ̀yà, ìjà òmìnira fáwọn àgbẹ̀ ni àbí ìfẹ̀míṣòfò?
Ọ̀kan nínú àwọn ìwé tí àwọn #RevolutionNow fi síta kà pé "Ẹ darapọ̀ mọ́ wa nínú ìwọ́dé June 12" Kò sí òsì, ebi, àti ètò ààbò tó mẹ́hẹ mọ́ ni Nàìjíria... "Ó tó gẹ́ẹ́! kò sí nǹkan tó le dá ẹ̀ni tí àsìkò rẹ̀ ti tó"

Oríṣun àwòrán, Omoyele Sowore /Facebook
Àwọn ìwé míràn tí wọ́n tun lẹ̀ ní ètò ìwọ́de tí yóò wáyé ni Germany, tí àkọlé rẹ̀ sí jẹ́ " O di dadan kí Buhari lọ" Ẹ jẹ́ kí a kóra jọpọ̀ láti lé ìjọba tó ń ṣonígbọ̀wọ́ ìwà ìgbásùmọ̀mi.
Ọ̀nà tí kò dára, ọ̀wọ́n gógó epo pẹ̀tiró, ilé ìwòsàn tí kò dára, èto ọ̀rọ̀ ajé tó n wọ́lẹ̀, ìwà ìkà ọlọ́pàá àti àibìkítà fún òfin, àti ètò ẹ̀kọ́ tó ti dójúdé.
Bákan náà ni àkọ́le tí àwọn New York lorílẹ̀-èdè America, Kaduna àti Abuja ṣe sọ, tí ọ̀rọ̀ ẹgbẹ̀rún lọ́na ọgbọ̀n nàìra gẹ́gẹ́ bí owó oṣù nígbà tí mílíọ̀nù mẹ́tàlá jẹ́ owó owó oṣù àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ asòfin.
Gbogbo àwọn ìwé ìpolongo fún ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn ni wọn fi àkọlé Buhari "Must Go" sí, èyí ti àwọn olùwọ́de sì wá láti Toronto ( Canada) Austin (Texas USA) Calabar, Kebbi àti Lagos.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileesẹ́ Ọlọ́pàá ní kí aráàlú jòkó sílé yín
Ẹ̀wẹ̀, ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ní ọ̀pọ̀ ìpínlẹ̀ jákèjádò orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó fi mọ́ Eko, Bayelsa, Kogi, Cross River, Delta, Edo, Ekiti, àti Akwa Ibom sọ pé, àwọn kò gban pé ètò ìwọ́de kanakan yóò wáye.
Sùgbọ́n o, ìpínlẹ̀ bi Kwara àti Oyo lásìkò ètò ìgbaradì tí wọ́n má ń pè ní "Show of Force lánàá ni àwọn ṣetan láti tẹ̀lé ìlànà ofin bótilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn kan ń pinu láti ṣe ìwọ́de ìfẹ̀họ́nuhàn.
Sùgbọ́n olùṣágbátẹrù " #RevolutionNow Omoyhele Sowore, sọ fún ìwé ìròyìn Punch pé nínú àtẹjíṣẹ́ lóríṣiríṣí pé kò sí òfin tó sọ pé kí ọmọ Nàìjíríà ma fẹ̀hónùhàn.
Ó ní ọlọ́paàá kò lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ pé kí ará ìlú má wọde
June 12 jẹ́ àyájọ ọjọ́ ìjọba araarawa ni tòótọ́, tí ètò ìbò tí kò lẹ́jańbákan nínú sì wáyé
Sowore ṣàlàyé pé ìdí tí ìwọ́de fí n wáye láwọn orílẹ̀-èdè míítràn ni pé ìwáde apapọ̀ láti dá ètò ìjọba àwaarwa padà ni.
Bákan náà ni Sowore bẹnu àtẹ́ lu àtẹ́jáde ọlọ́paàá tọ ń kìlọ fún àwọn ẹgbẹ́ jẹgbẹ́ láti wá gba àṣẹ sáájú àsìkò ìwọ́de, ó ní kò sí nǹkan tó jọ́ bẹ́ẹ̀ " Kódà láye àwọn ológun à kò nílo láti gbààyè lọ́wọ́ ọlọ́pàá kí a tó wọ́de ìfẹ̀hónúhàn.
Bákan náà ni olùṣagbátẹ̀rù " Concerned Nigerians" Deji Adeyanju náà bẹ̀nu àtẹ́ lu ìdúkoko ọlọ́pàá, pé kò sí ìdí kankan láti máa dí àrá ìlú lọ́wọ́ láti lo ẹ̀tọ́ wọn.
















