EndSARS protest: Ikọ̀ Operation Burst gba ìgboro kan n‘Ibadan

Ninu ibẹrubojo ni ọpọlọpọ awọn olugbe ilu Ibadan wa bayii nitori iwọde awọn ikọ ologun "Operation burst".
L'owurọ Ọjọru ni ibọn awọn ikọ naa n dun lakọlakọ ni agbegbe Baṣọrun.
Bakan naa ni wọn tun ṣe iwọde kaakiri awọn agbegbe bi i Oluyọle, Bẹẹrẹ, Adeọyọ, Iwo road lati ko awọn nnkan ti awọn olufẹhonuhan fi di opopona kuro loju ọna.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ọ̀kan lára olùwọ́de tó fara gbọgbẹ́ ní Lekki jáde láyé - Sanwo-Olu
- Kò sí olùwọ́de tó kú ní Lekki - Sanwo-Olu
- N kò lọ́wọ́ nínú ìpànìyàn, kò dáa bí wọn ṣe lo ọta ìbọn ní Lekki - Tinubu
- Ọjọ́ Ìsẹ́gun di ọjọ́ ìbànújẹ́ fún ọ̀pọ̀ ìdílé ní Nàíjíríà torí òkú tó ṣùn
- Ọ̀dọ́ 30 ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́ nílé ìwòsàn torí ọ̀gbẹ́ ìbọn ní Lekki - Sanwo-Olu ṣàlàyé
- Àwọn ṣọ́jà ṣíná ìbọn bolẹ̀ ni Lekki Tollgate
- Àwọn ọlọ́dẹ darapọ̀ mọ́ ìwọ́de #EndSARS l'Osogbo, wọ́n ní kò sáyè fún jàǹdùkú mọ́
Ọpọlọpọ awọn ontaja lo ti ṣọọbu wọn pa, eeyan perete lo si n rin n'igboro gẹgẹ bi awọn ẹlọmii ṣe deju molẹ pẹlu ifoya.

Awọn agbegbe bii UI, General gas to fi mọ Ajibọdẹ, Sango ati Ọjọọ lo da paroparo.
Ijade ikọ ologun naa ni ko se lẹyin ikọlu ni awọn janduku kan ṣe si agọ ọlọpaa to n bẹ ni agbegbe Ọjọọ lọsan ọjọ iṣẹgun nibi ifẹhonuhan #ENDSARS.
Atẹjade lati ọwọ Kọmisọna ajọ ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ, Joe Nwachukwu Enwonwufi idi rẹ mulẹ wi pe, awọn janduku naa dana sun agọ ọlọpaa to wa ni Ọjọọ.

Bakan naa lo ni wọn ṣekupa ọlọpaa meji bẹẹ sini awọn ọlọpaa meji mii ti di awati.
Kọmisọna ajọ ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ fi kun ọrọ rẹ pe, awọn janduku naa tun yawọ ibi ti wọn n ko nnkan ijagun si ti wọn si ko awọn ibọn AK- 47 kan lọ.

Nibayii gbogbo ifẹhonuhan #ENDSARS ni awọn ọdọ ti so rọ jakejado ipinlẹ Ọyọ, wọn ṣe ikede naa l'ọjọ Iṣẹgun.
Àwọn jàǹdùkú ti sọná sí Iléeṣẹ́ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ TVC àti ọkọ̀ akérò BRT l'Eko

Oríṣun àwòrán, @DirectorSolomon
Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni awọn eeyan kan ti sọ ina si ileesẹ agbohunsafẹfẹ TVC nilu Eko.
Bi o tilẹjẹpe isede wa nilu Eko, sibẹ ko ye ẹnikẹni bawọn eeyan naa se raye wa jo ileesẹ naa.
Iroyin naa ni wọ̀n n jo ileesẹ ọhun, amọ a ko tii le sọ iye dukia to bajẹ nibẹ.
- N kò lọ́wọ́ nínú ìpànìyàn, kò dáa bí wọn ṣe lo ọta ìbọn ní Lekki - Tinubu
- Mò ǹ wá ọ̀dọ́ Lekki tó farapa láti fún wọn ní ìrànwọ́ - Anthony Joshua
- Ọ̀dọ́ 30 ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́ nílé ìwòsàn torí ọ̀gbẹ́ ìbọn ní Lekki - Sanwo-Olu ṣàlàyé
- Ọjọ́ Ìsẹ́gun di ọjọ́ ìbànújẹ́ fún ọ̀pọ̀ ìdílé ní Nàíjíríà torí òkú tó ṣùn
Awọn fidio ti awọn eeyan n fi lede loju opo Twitter fi han pe awọn janduku naa gbe epo kerosine lọwọ, ti wọn si n jo ọkọ akero to jẹ ti ileeṣẹ ọhun ninu ọgba wọn.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Bakan naa ni fidio ti ọkan lara awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ naa, Morayo Afolabi-Brown, fi fido lede loju opo Instagram rẹ, nibi to ti sọ pe awọn janduku naa ti se awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ naa mọle.

Oríṣun àwòrán, Gidi_Traffic/DirectorSolomon
Ọpọ eeyan lo gbagbọ pe agba oselu APC, Oloye Bola Tinubu lo ni ileesẹ naa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Ẹwẹ, awọn jaduku miran si ina si awọn ọkọ akero ijọba ipinlẹ Eko, BRT ni Oyingbo.
A n se akojọpọ ẹkunrẹrẹ iroyin yajoyajo lọwọ, a o maa gbe ẹkunrẹrẹ iroyin naa sori atẹ iroyin wa laipẹ. Ẹ jọwọ, ẹ tun oju opo iroyin yi yẹwo, ki ẹ lee ri ẹkunrẹrẹ iroyin ọtun laipẹ.












