Democracy Day: Wo ipa mánigbàgbé Obasanjo, Yar‘adua, Jonathan àti Buhari ní Nàíjíríà

Aworan awọn aarẹ Naijiria to jẹ kọja lati igba taa bẹrẹ ijọba alagbada

Ọdun miran tun ti de tawọn ọmọ Naijiria n ṣe ayajọ ijọba awarawa Democracy Day.

Lati igba ti Naijiria ti pada si ijọba alagbada ni ọdun 1999 awọn ijọba mẹrin lo ti ṣe akoso ilẹ naa.

Ninu itan, awọn ọmọ Naijria a maa kọ rere awọn kan ninu wọn ti wọn a si tun maa fi idakeji adura ranṣẹ si omiran fun bi wọn ṣe ṣejọba.

Àwọn ìtàn mánigbàgbé tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ni meni meji, diẹ ree lara awọn nkan manigbagbe ti o so mọ ijọba mẹrẹẹrin to ti jẹ ni Naijiria lati ọdun2009.

Olusegun Obasanjo:

Odu ni Oloye Olusegun Matthew Okikiola Aremu Obasanjo, kii ṣe aimọ foloko lagbo oṣelu Naijiria.

Ṣaaju ki o to bọ aṣọ ologun silẹ lati darapọ mọ oṣelu awarawa, Obasanjo ti fi igba kan dari Naijiria, to si ko ipa ribiribi nigba ogun abẹle Biafra to ja ni Naijiria.

Ipadabọ ẹbọra Owu si agbo oṣelu waye lẹyin to ṣẹwọn ti iku si tun re kọja lori rẹ labẹ ijọba ologun Sani Abacha.

Aworan aarẹ tẹlẹ Olusegun Obasanjo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Oloye Obasanjo gun ori alefa gẹgẹ bi aarẹ Naijiria alagbada lọjọ Kọkandinlọgbọn oṣu Kaarun ọdun 1999.

Lara awọn ipa ati ohun manigbagbe to waye lasiko ijọba Obasanjo la ti ri ka pe :

  • O jẹ ki awọn ọmọ Naijiria gbadun ẹtọmọniyan lati sọ ero ọkan wọn eleyi to nira labẹ ijọba ologun Sani Abacha
  • Labẹ ijọba Obasanjo ni wọn ti da ajọ ICPC ati EFCC silẹ lati koju iwa ajẹbanu
  • Ijọba Obasanjo ribi gba anfaani aforiji gbese ti Naijiria jẹ awọn ẹgbẹ ilẹ okere Paris and London Club to le ni biliọnu mejidinlogun dọla
  • Obasanjo gbiyanju lati mu adinku ba iya ohun iṣẹ to koju awọn ọmọ Naijiria. O fi kun owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ lasiko ijọba rẹ

Kudiẹkudiẹ ijọba rẹ:

  • Third Term Agenda. Igbiyanju Obasanjo lati ṣe saa kẹta yi jẹ iṣẹlẹ to ta ẹrẹ si aṣọ aala iṣejọba Obasanjo
  • Awọn ọmọ Naijiria kan ko dunnu si Obasanjo pẹlu bo ti yọnda Bakassi fun orileede Cameroon
  • Iṣekupani lati ọwọ awọn ọmọ ologun Naijiria lagbegbe Zaki Biam lab aṣẹ aarẹ Obasanjo nitori bi awọn eeyan ibẹ ṣe pa ọmọ ologun Naijiria
  • Ẹsun idunkoko mọ ati lilo EFCC lati fi doju le awọn ọmọ ile aṣofin Naijiria ati ẹnikẹni to ba ri pe wọn tako ijọba rẹ
  • Awọn ọmọ Yoruba ẹgbẹ rẹ gbagbọ pe Obasanjo ko ṣe to lati mu idagbasoke ba ẹya Yoruba paapa nipa ipese awọn ohun amayedẹru

Umaru Musa Yar'Adua:

Ọmọ bibi ipinlẹ Katsina ni Yar Adua to si figba kan di ipo Gomina mu ki Olusegun Obasanjo to fa kalẹ lati jẹ aarẹ Naiajiria.

Labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu PDP ni wọn yan lati du ipo aar to si jawe oulbori ninuidibo to waye lọdun 2007.

Nigba ti yoo fi de si ori oye, pupọ awọn eeyan lo n pariwo pe eto idibo to gbe dori alefa ni kọnunkọhọ ninu.

Umar Musa 'Yar Adua (1951-2010)

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Yar Adua ṣe ohun to ya ara ilu lẹnu nigba to sọ pe oun gba pe lootọ ni eto idibo to gbe oun de ori oye ko yanrantin.

Koda o tun sọ fun awọn alatako lati kọri si ileẹjọ tako esi ibo ti ko ba tẹ wọn lọrun.

Ni itẹsiwaju ipinnu yii, awọn eto ilana ati iyipada de ba eto idibo Naijiria.

Pataki julọ, Yar Adua ṣe agbekalẹ Igbimọ kan labẹ idari Adajọ agba Justice Uwais lati ṣe agbeyẹwo ati atunṣe eto ilana idibo Naijiria.

Jonathan

Oríṣun àwòrán, Facebook

Lara awọn nkan manigbagbe ti igbimọ yi fi lelẹ lo pada wa jẹ gẹgẹ bi itẹlẹ fun eto idibo Naijiria to ti lalaafia de ibi to ni loni.

Awọn nkan mii to ṣe lasiko rẹ to jẹ manigbagbe ni:

  • O paṣẹ ki wọn san owo ijba ibilẹ ipinlẹ Eko ti ijọba Obasanjo gbẹsẹ le
  • O ṣe agbekalẹ eto aforijin fawọn ajijagbara Niger Delta,Amnesty Programme
  • Ijọba rẹ lo kọkọ mu adinku ba owo epo bẹntiroo lati N75 si N65

Eeyan ki wa ki o ma ni alebu tiẹ

Ibaṣepọ laarin ijọba Yar Adua ati awọn oloṣelu kan ti ọwọ wọn ko mọ jẹ ohun to mu ki awọn eeyan foju abuku wo ijọba rẹ.

Apẹrẹ eleyi lo han pẹlu bi ijọba rẹ ṣe dunkoko mọ Nuhu Ribadu titi ti wọn fi yọ nipo ọga agba EFFC ti wọn si fi Farida Waziri rọpo rẹ.

Nuhu Ribadu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lakotan, ai ṣe eto igbejọba kalẹ fun igbakeji rẹ Goodluck Jonathan da ọpọ wahala silẹ nigba ti aarẹ de ba a.

Abalọ ababọ, Yar Adua pada ku sori oye lọjọ kaarun oṣu Kaarun ọdun 2010.

Goodluck Ebele Jonathan:

Goodluck Ebele Jonathan wa lara awọn oloṣelu Naijiria ti awọn eeyan a maa juwe bi ẹni itan.

Nigba ti yoo fi de ori oye, pupọ ni ko lero wi pe ipo aarẹ le kan.

Saaju asiko yi, iyọnipo Gomina ti o jẹ igbakeji rẹ Diepreye Alamisegha lo mu ki Jonathan di Gomina ipinlẹ Bayelsa.

Aworan Goodluck Jonathan ati aarẹ Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, TWITTER/GARBA SHEHU

Iru nkan to mu di Gomina tun ṣẹlẹ nigba ti aarẹ Umaru Musa Yar Adua papoda.

Ninu awọn nkan manigbagbe ti ọmọ Naijiria fi maa n ranti ijọba rẹ ni bi o ti ṣe gbe ijọba kalẹ lẹyin to fidirẹmi ninu idibo aarẹ.

Igba akọkọ ree ninu itan Naijiria ti aarẹ to wa lori oye yoo fidirẹmi ninu idibo ṣugbọn o finu fẹdọ gbe ijọba kalẹ fun Muhammadu Buhari to wa lori oye loni.

Awọn nkan iranti to ṣe lasiko ijọba rẹ ree:

  • Boko Haram ati awọn agbesunmọmi gbode ni Naijiria
  • Iwa ajẹ́banu ati lilu owo ọba ni ponpo gbilẹ lasiko ijọba rẹ. Titi di baa ṣe n sọ yi, iyawo rẹ n jẹjọ iwa ajẹbanu
  • Airiṣẹ gbode kan lasiko rẹ ti ọpọ si n ke irora ọwọngogo epo bntiroo ti o fi owo kun

Muhammadadu Buhari:

Ọgagun tẹlẹ ri Muhammadu Buhari ni aarẹ to wa lori oye lọwọ lọwọ ni Naijiria.

O di aarẹ lẹyin igba kẹrin to gbiyanju lati dije ipo naa.

Saa keji rẹ lo n lo lọwọ bayi ti orisirisi nkan si ti waye lati igba to de ori oye.

Orin mo de lati wa koju iwa ajẹbanu ati mu alaafia pada ba ilu ni o fi ṣe ipolongo rẹ eyi to mu ko ṣi aga nidi Goodluck Jonathan to wa lori oye.

Nitori pe Buhari ko ti pari lilo ipo rẹ gẹgẹ bi aarẹ, o ṣeeṣe ki a ma le mẹnu ba gbogbo ohun manigbagbe to waye labẹ ijọba rẹ.

Ṣugbọn ni iwọnba ti aye le gba wa, a o ṣapa lati darukọ diẹ nkan to gbeṣe ni saa kini rẹ ati eyi to n ṣe lọwọ

  • Buhari doju ija kọ awọn to n hu iwa ajẹbanu ti ijọba rẹ si gbe pupọ lọ si ile ẹjọ
  • Labẹ ijọba Buhari igbiyanju waye lati gba awọn owo pada lọwọ awọn to ji owo ilu ko botilẹ jẹ pe awọn alatako ni ojuṣaju wa nibẹ
  • Nibẹrẹ pẹpẹ ijọba Buhari, wọn lawọn koju igbesunmọmi ati awọn ipenija aabo ṣugbọn ko jọ pe wahala yi ti dopin
  • Ijọba Buhari kede awọn eto igbayegbadun fara ilu paapa eyi to fi pese iṣẹ fawọn ọdọ ati alaini lawujọ, Npower ati Trader Moni wa lara wọn
  • Ijọba Buhari gbajumọ ipese ohun amayedẹrun bi oju ọna,reluwee,papa ofurufu ati bẹbẹẹlọ
Ikede kan lori Yoruba Nation

Oríṣun àwòrán, sunday_igboho1/nstagram

Awọn ohun ti araalu ko dunu si

Ẹsun kan tawọn araalu n ran lẹnu lori ijọba aarẹ Buhari ni pe o faye gba iwa ẹlẹyamẹya pupọ ti ko si fi tawọn ẹya to ku ṣe ninu iṣejọba rẹ.

Lọpọ igba ni Ijọba Buhari tako ẹsun yi to si ni pe ọrọ ko ri bẹ.

Bakan naa awọn ọmọ Naijiria ko dunu si bi ijọba Buhari ko ti ṣe mu awọn ileri to ṣe ṣẹ paapa julọ nipa aabo ati ipese ayika alaafia fun araalu.

Wahala ijingbe, ikọlu laarin awọn darandaran ati agbẹ, ifapajanu awọn ajijiagbara ati awọn kudiẹkudiẹ mi tabuku ijọba yi lọdọ araalu.

Awọn ọmọogun orilẹede Naijiria nipinlẹ Borno

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Awọn ọmọogun ko sinmi fifigba gbaga pẹlu awọn janduku orisirisi ni Naijiria

Awọn ikunsinu wọn yi pọ debi pe awọn ọdọ Naijiria ṣe iwọde ENDSARS eyi to ṣafihan bi inu wọn ko ti ṣe dun si ijọba paapa awọn agbofinro to n dunkoko mọ araalu.

Lọwọlọwọ, eyi tawọn eeyan kan n ba ijọba fa ni wahala pe awọn f yapa kuro lorileede Naijiria ti elyi si mu ki awọn ẹya bi Yoruba ati Igbo maa ni ki onikaluku maa ṣe tiẹ.

IPOB ni ilẹ Igbo ati Ẹgbẹ awọn ọmọ Yoruba to n pe fun idasilẹ orileede Yoruba lo lewaju awọn ajijagbara to n fi ojojumọ kesi aarẹ ki o tu Naijiria ka kawọn ya sọtọ.

Awọn ipenija yi titi di oni taa n ṣe ajọdun ijọba awarawa ni Naijiria ṣi wa nilẹ.

Bi ijọba Buhari yoo ti ṣe wa tukọ orileede yi lawọn eeyan n wo ki awọn araalu ba le jẹ anfaani ti wọn tori rẹ korajọ ṣe ajọdun Democracy Day.