Àyájọ́ June 12: Ìsinmi di ọdún tó ń bọ̀

Aworan Ọmodekunrin kan to ko asia lọwọ

Oríṣun àwòrán, PIUS UTOMI EKPEI/AFP/Getty

Àkọlé àwòrán, Ọmodekunrin kan ko asia orileede Naijiria lọwọ lọjọ ayajọ òṣèlú tiwá n tiwá
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Bí o ba n f'ọkan sí pe ìsinmi yoo wa ni ayajọ ọjọ ijọba tiwá n tiwá lọjọ kejìlá oṣù kẹfà, yara tètè mú ọkàn kúrò níbẹ. nitori kò sí òhun tó jọ rárá.

Ìjọba àpapọ̀ orílèèdè Nàìjíríà ló ṣàlàyé ọrọ yíi lójú òpó Twitter ilé iṣẹ Ààrẹ.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Atẹjade náà ní, àlàyé yii ṣé pàtàkì pẹlú bí àwọn èèyàn ṣé n béèrè pé, ṣé ìsinmi yóò wá tàbí kó ní sí.

Ìkéde náà tèsíwájú pé, ni ìbámu pẹlú òun tó wà nínú atẹjade to tí wáyé ṣáájú, ìsinmi yóò maa waye lọjọ Kejìlá oṣù Kẹfà ọdọọdun, gẹgẹ bíi ayajọ ọjọ ijọba tiwá n tiwá dipo ọjọ kokandinlogbon osu karun ti a mọọ̀ si tẹlẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Laipe yii ni Ìjọba àpapọ orílẹ̀-èdè Nàíjíríà kéde ọjọ́ kejìlá, oṣù Kẹfa (June 12) gẹ́gẹ́ bíi àyájọ ọjọ́ iṣèjọba awa-ara-wa dipo ọjọ́ kọkandinlọgbọn, osu karun-un (May 29) to maa ń wáyé l'ọdọọdun.

Ààrẹ Muhammadu Buhari ni awọn kéde ọjọ yii, lẹ́yin ìjíròrò pẹ̀lú àwọn èèkan lórílẹ̀-èdè Nàíjíríà, to si tun fi ami ẹyẹ to ga julọ ni orilẹede yii da MKO Abiọla, ti gbogbo agbaye gba pe o moke ninu ibo naa, lọla.