Yoruba Council of Elders: Ìgbìmọ̀ Àgbààgbà Yorùbá ké sí Ààrẹ Buhari pé kó kọ̀wé fipò sílẹ̀ lórí ipò tí Nàìjíríà wà

Igbimọ awọn agba ilẹ Yoruba ti ke si aarẹ Muhammadu Buhari pe asiko to fun un lati kọwe fi ipo rẹ silẹ.
Akọwe agba fun ẹgbẹ naa, Dokita Kunle Ọlajide ṣalaye eyi ninu ifọrọwerọ kan pẹlu BBC News Yoruba.
Dokita Ọlajide ni nibi ti ọrọ de duro bayii o fihan gbangba pe Aarẹ Buhari ko ni ohun to yẹ lati tukọ orilẹede Naijiria mọ, ko lọ sinmi lo ku.
- Ṣé lóòtọ́ ni pé ilé iṣẹ́ ọmọogun òfurufú ṣèèsì ju àdó olóró síbi ayẹyẹ ìgbéyàwó kan?
- Ọká fóó! Oníṣègùn tó gba 250M owó ẹbọ lọ́wọ́ aláìsàn kó sọ́wọ́ EFCC
- Alaseyori kọ́ ló ni orin "Oniduro Mi", àmọ́ ìdí tí mi ò ṣe bá a jà pé ó jí orin mi kọ nìyìí - Tolu Adelegan
- Kò sí olùfẹ̀hónúhàn kankan ní àhámọ́ ọlọ́paà nítorí ìwọ́dé June 12 - Frank Mba
O ni ohun ti o n damu orilẹede Naijiria bayii ni iwe ofin rẹ ati pe o digba ti atunṣe ba de ba iwe ofin naa ki orilẹede Naijiria to lee toro.
O ni orilẹede Naijiria nilo ki awọn eeyan rẹ parapọ joko ki wọn wa jumọ sọrọ lori irufẹ ofin ti wọn fẹ.
O sọ pe, "Awọn ijọba Ipinle ati awọn alaṣẹ ibile gbọdọ dide ni iṣọkan lati pade Aarẹ ati beere lọwọ rẹ boya a tun fẹ wa ni Nigeria."
Igbimọ agba Yoruba kọminu lori ikọlu awọn agbebọn darandaran nilẹ Yoruba leyi to ni o buru de odo ikun pe ijsba ko ri ojutu sii.









