Tope Alabi, Adeyinka Alaseyori on Oniduromi: Shola Allyson, Lanre Teriba àtàwọn èèkàn míràn sọ̀rọ̀ lórí ohun tí Tope Alabi sọ nípa orin 'Oniduro mi'

Oríṣun àwòrán, Facebook
Afẹfẹ awuyewuye lori ọrọ ti gbajumọ olorin ẹmi, Tọpẹ Alabi sọ nipa orin Oniduro mi ẹ ṣeun ṣi n fẹ kaakiri bayii.
Koda, afẹfẹ naa ti fẹ kan awọn olorin ẹmi atawọn gbajumọ awọlumatẹ bayi lorilẹede Naijiria ati loke okun.
Shola Allyson lo kọkọ bọ sigboro aye lati sọ ero tirẹ lori ọrọ naa leyi to ni o ku diẹ kaa to.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wọ́n gbé Bobrisky dìgbà-dìgbà padà sílé ìwòsàn lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ ìdí
- Wo oríadé méje tí ẹ̀ṣùn ìwà ìjínigbé ṣí mọ́ lórí
- Ṣé lóòtọ́ ni pé ilé iṣẹ́ ọmọogun òfurufú ṣèèsì ju àdó olóró síbi ayẹyẹ ìgbéyàwó kan?
- Ọká fóó! Oníṣègùn tó gba 250M owó ẹbọ lọ́wọ́ aláìsàn kó sọ́wọ́ EFCC
- Alaseyori kọ́ ló ni orin "Oniduro Mi", àmọ́ ìdí tí mi ò ṣe bá a jà pé ó jí orin mi kọ nìyìí - Tolu Adelegan
- Ṣé lóòtọ́ ni pé ilé iṣẹ́ ọmọogun òfurufú ṣèèsì ju àdó olóró síbi ayẹyẹ ìgbéyàwó kan?
Ninu ọrọ to fi soju opo ayelujara Instagram rẹ, Shola Allyson ni orin ẹmi ti wọn n sọ yii, ti di eyi to ti bukun ọpọlọpọ eeyan kaakiri agbaye, ninu eyi ti oun pẹlu naa ti kọ ẹya orin toun nibẹ.
Akọrin "ifẹ bi eji owurọ" naa to ni ẹnu Mama Bọla Arẹ loun ti kọkọ gbọ orin naa nilu Akurẹ lọdun diẹ sẹyin, wa kan sara si Adeyinka Alaṣeyọri to sọ sorin naa di gbajugbaja,
O tun kan saara si Alaseyori fun bo ṣe mu orin naa wa si etigbọ ọpọlọpọ eeyan, to si ti mu iyanu ba aye wọn pẹlu.
Bakan naa ni akọrin ẹmi miran, Lanre Tẹriba naa ko ṣai da si ọrọ naa.
Nibi ayẹyẹ kan ti Yinka Alaṣeyọri atawọn eekan lawujọ miran wa, ni Lanre Tẹriba ti bu ẹnu atẹ lu ọrọ ti Tọpẹ Alabi sọ naa to si ni ko si idi fun un lati maa bu ẹnu atẹ lu olorin miran.
O ni Tope Alabi gan pẹlu ti fi ọpọlọpọ orukọ miran ṣakawe Ọlọrun, ti ko si si ẹnikẹni to dide takoo.
"Sebi awọn kan lo pe Ọlọrun ni o wọ kẹmbẹ re ibi ija, ṣe wọn mọ telọ to ran aṣọ Ọlọrun ni...katikati Catastrophy"
Ninu ọrọ tirẹ lori eto kan to ṣe loju opo Instagram rẹ lọjọ Aiku, Adeyinka Alaṣeyọri yẹra fun sisọ ọrọ lori iṣẹlẹ naa, eleyi to tun mu ki ọpọlọpọ awọn ololufẹ rẹ tun kan sara sii.



















