Yoruba Nation: Aseyin ní inú ìlú kò dùn, ìwọ́de sì le fa làásìgbò

Asẹyin tilu Iseyin, Ọba Abdulganiy Salau Ologunebi Ajinasẹ Kinni ti ke si awọn eeyan to n pariwo fun idasilẹ orilẹede Yoruba lati mase de ilu Iseyin lasiko yii.
Asẹyin, paroko ọrọ naa ransẹ si asaaju ikọ ajijagbara fun ilẹ Yoruba, Oloye Sunday Igboho ati awọn ikọ rẹ lasiko to n ba akọroyin Punch sọrọ.
Asẹyin ni ilu naa n sọfọ awọn eeyan mẹrin ti awọn asẹbode pa lọwọ, ipo ti wọn si wa bayii ko fara mọ iru iwọde bayii.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Baba Ijesha gba béélì níléẹjọ́ Májísírétì, àmọ́ ọ̀rọ̀ kù kó tó jáde l’àhámọ́
- Sunday Igboho lọ sọ́dọ̀ Guru Maharaji lórí ìdásílẹ̀ Yoruba Nation
- "Sunday Igboho kò fí lààkáyé kún ìjìjàgbara rẹ̀ nípa àtakò sí ìbò 2023"
- Mò ń wá olè tó jí nńkan ní ọọ́físì mi, ẹ̀bùn owó iyebíye rèé - Afeez Eniola
- Ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ìlú Modakeke àti Ile Ife
- Ṣé lóòtọ́ọ́ ni Baba Ijesha ti jáde ní àhámọ́ ọlọ́pàá?
- Ìròyìn òfegè táwọn èèyàn ń gbé kiri lórí ìjà Israel àti Palestine rèé
- Ohun tí àwon Gómìnà egbẹ́ òsèlú PDP fenukò lé lórí rèé nílùú Ibadan
- Nǹkan dé o! Àwọn àgbébọn tún yìnbọn pa ọlọ́pàá méjì lẹ́nu iṣẹ́, wọ́n dáná sun àgọ́ ọlọ́pàá
O ni iwọde naa lee mu laasigbo dani nitori ara n kan awọn eeyan ilu naa lọwọ tori ọfọ awọn ọmọ wọn ti wọn ku lairotẹlẹ.
"Lootọ ni mo sọ pe wọn ko gbọdọ gbe iwọde Yoruba Nation wa silu Iseyin. Ilu wa ko si ninu idunnu fun iru iwọde bayii.
Eyi ko si sẹyin isẹlẹ to waye lọsẹ to kọja."
Bẹẹ ba gbagbe, awọn osisẹ asọbode lo dede yinbọn pa eeyan mẹrin lọjọbọ ọsẹ to kọja, tii se ọjọ ọdun itunu aawẹ.
Isẹlẹ naa si waye lasiko ti awọn asọbode n le awọn onifayawọ to ko irẹsi wọle lọna to lodi sofin.













