Baba Ijesha: Látìgbà tí mo ti dé láhámọ́ ọlọ́pàá ni mo ti ń rí ẹ̀jẹ̀ nínú ìgbọ̀nsẹ̀ mi

Àkọlé fídíò, Baba Ijesha: Látìgbà tí mo ti dé láhámọ́ ọlọ́pàá ni mo ti ń rí ẹ̀jẹ̀ nínú ìgbọ̀nsẹ̀ mi

Lẹyin ti ile ẹjọ gba oniduro rẹ lori ẹsun aṣemaṣe pẹlu majesin ti wọn fi kan an, gbajumọ oṣere tiata, Ọlanrewaju James ti ọpọ mọ si Baba Ijẹṣa, ti pariwo sita pe oun n ri ẹjẹ ninu igbọnsẹ oun.

Baba Ijẹṣa sọrọ soke ninu fidio kan to n ja ranyinranyin kaakiri lori ayelujara nibi ti wọn ti n se ayẹwo ara rẹ ni ileewosan to ti lọ gba itọju.

Ninu fidio naa ni Baba Ijesha ti salaye pe lati igba ti oun ti ti ahamọ ọlọpaa de, ilera oun ko ri bakan naa mọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Baba Ijesha ni wọn fi bata gba oun lori lọpọ igba ati ni bẹbẹrẹ idi lasiko ti oun wa ni ahamọ, eyi to ni o wa lara idi ti ilera oun ko fi ji pepe mọ.

Nigba to n dahun ibeere ti dokita n bii, Baba Ijesha dahun pe "Bi igba ti wọn n lu olu lori mi lo ṣe maa n ri, bi ori ba n fọ mi, ti irora rẹ si maa n kọja afarada."

Ni Ọjọbọ, ọjọ kẹrinlelogun oṣu kẹfa ọdun 2021 ni ile ẹjọ gba oniduro Baba Ijẹsha lẹyin ọpọlọpọ ọsẹ ni ahamọ ọlọpaa ni Panti nilu Eko.

Àkọlé fídíò, Jeleosinmi Art Centre: Ibùdó yìí ló ń tọ́ ọ̀dọ́ sọ́nà nípa iṣẹ́ ọnà àti àṣà dípò ìwà àìda