Ataga Murder: Fásitì UNILAG sọ̀rọ̀ sókè lórí Chidinma, akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ tó pé òun ló pa Usifo Utaga

Ataga Murder: Ẹ Jọ̀wọ́, ẹ gbà mi mí o fẹ́ kú- Chidima ti wọn fẹ̀sùn kan pé o pa olùdásílẹ̀ SuperTV

Adari Ileewe Giga Fasiti ti Eko, UNILAG, Ọjọgbọn Oluwatoyin Ogundipe ti ni ileewe giga naa n tẹlẹ gbogbo alakalẹ to yẹ lori iṣẹlẹ ipaniyan ti akẹkọọ ileewe naa jẹwọ pe oun lo wa nidi rẹ.

Ọjọgbọn Ogundipe sọ ọrọ yii lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ lori awọn iṣẹlẹ to sọ bi akẹkọọ fasiti ileewe giga UNILAG, arabinrin Chidinma Adaora Ojukwu ṣe ṣekupa Usifo Ataga to jẹ oludari ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ Super TV.

Ogundipe ni awọn ko le sọ wi pe awọn ko mọ akẹkọọ naa ri nitori ọmọ ileewe awọn ni, bo ti lẹ wu ki iṣẹlẹ naa le to.

''Ninu akọsilẹ to wa ni ileewe naa ni a ti ri pe eni ti yoo duro fun un ti ohunkohun ba ṣẹlẹ si ni Arakunrin Onah Ojukwu.''

Ọmọ ileewe fasiti yii, to wa ni ipele kẹta nibi ti o ti nkọ imọ eto ẹkọ nipa eto iroyin, pẹlu nọmba idanimọ- 170912015.

''A ko le lailai sọ wi pe kii ṣe ọmọ ileewe wa nitori iṣẹlẹ to waye naa''

Lori ibeere pe kini awọn oludari ileewe naa n se nipa iṣẹlẹ naa, Ogundipe ni awọn n tẹle alakalẹ to ye lori iṣẹlẹ ọhun.

''Nitori iṣẹlẹ naa ti di ti gbogboogbo, ti ileeṣẹ ọlọpaa si ti n gbe igbesẹ le lori, awa naa n ṣe tiwa gẹgẹ bi ileewe rẹ.''

Ọsẹ to kọja ni ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko fi oju Chidinma han fun gbogbo eniyan,lẹyin to jẹwọ pe lootọ ni oun pa Ataga, ti oun si kọkọ yin lọrun, ki oun to gun lọbẹ pa.

Olórin bíi Tiwa Savage ni mo fẹ́ jẹ́ lọ́jọ́ ìwájú, ẹ má jẹ́ kí ń kú - Chidima afurasí apààyàn

Àkọlé fídíò, Glorious Twins: Taiwo àti Kehinde Ekundayo ní ọ̀dọ́ ìyá àgbà ní àwọn ti ẹ̀bún orin kíkọ

Chidima Ojukwu ti wọ́n fẹ̀sùn kan pé ó pa olùdásílẹ̀ ilé iṣẹ́ amóhùnmáwòràn SuperTV Usifo Ataga, ti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ìdílé ọkùnrin náà láti dárí jì òun.

Nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ to ṣe pẹ̀lú ìlé iṣẹ́ ìròyìn Punch ló ti bẹ̀bẹ̀ pé òun kò fẹ́ kú lórí ọ̀rọ̀ yìí.

Ọmọbinrin náà tó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ni fásìtì Eko tẹ̀kúntẹkún ló n sọ̀rọ̀ pé òun kábàmọ̀ pé òun pa Ataga.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Mí o mọ̀ ohun tí ọjọ́ iwájú mí n sọ sùgbọ́n mí o fẹ́ kú. Ẹ̀ jọ̀wọ́ mí ò fẹ́ kú nítórí ẹjọ́ yìí, Mí o pa ènìyàn kankan ri láyé mi.

" Mò ń gbìyànjú láti pa ìmọ̀ mí pọ̀ ni kìí ṣe pé n kò kábàmọ̀ nǹkan ti mo ṣe lásìkò tí àwọn ọlọ́pàá ń fi mi hàn fún àwọn oníròyìn, àwọn kan sọ pé mí ò tílẹ̀ ṣe bí ẹni tó nímọ̀lára nǹkan ti mo ṣe.

Àkọlé fídíò, Kò sí ẹni tí mo fura sí lórí ikú ọkọ mi, àmọ́..- Adebisi aya Titus Ejanla tí wọ́n pa ní Ib

Mo kábàmọ́ọ̀ pé mo ṣe nǹkan ti mo ṣe, mo sì tọrọ àforíjì, ẹbí ọ̀gbẹ́ni Ataga mo tọrọ àforíjì fún nǹkan ti mo ṣe.

" Tí mo bá ni àǹfàní ẹlẹ́kejì mi ò ni ṣe irú lrẹ̀ mọ́ láyé mi, ẹ jọ̀wọ́ ẹ dáríjì mi."

Sááju ní ìròyin kan pé Chidima gba ilé àyágbé kan si agbègbè Lekki ti wan sì padà bá okú Ataga ni ọjọ́ kejì, èyí ló sì jẹ́ kí wọ́n fúra sí Chidima pé ó lọ́wọ́ nínú ikú náà.

Àwọn ọlọ́pàá ni àwọn lépa Chidinma tí wọ́n sì ri nilé bàbá rẹ̀ ni agbègbè Alagomeji ni Yaba.

Lẹ́yìn tí wọ́n mú, Chidinma ni bí òun ṣe hu ìwà ìpànìyàn náà kò ṣẹ̀yìn oogun olóró tí òun lò àti àwọn otí lílé.

Àkọlé fídíò, Peter Fatomilola: Robbery burú ju Yahoo lọ, iṣẹ́ ọpọlọ lọmọ Yahoo fi ń gba owó ìran baba

Bi ó ṣe lo ìgbà kékeré rẹ̀

Chidinma ni àwọn òbí òun pínyà láti ìgbà tí òun ti wà ni ọmọ ọdún méjì, tí òun sì bẹ̀rẹ̀ sí ní gbé pẹ̀lú èèyàn mọ̀lẹ́bí òun lọ́kùrin Chijioke Obi ni agbègbè Mushin nílùú Eko.

Ó fi kun pé lásìkò tí òun ń dàgbà, ìpinnu òun ni láti dí olórin tàbi eléré.

Afurasí náà ṣàlàyé pé, àwọn tí òun ń wò bi àwòkọ́ṣe ni Tiwa Savage, Beyounce, Rihanna, Genevieve àti Regina Hall, ọ̀dọ̀ ẹbi òun sì ni òun gbé, tó ń jẹ́ Chijioke Obi, mí o mọ̀ bóyá oun lo n jẹ́ Izu.

Àkọlé fídíò, Fulani attack, Ajowa Ondo: Àwọn Bororo yìí ti kọ́kọ́ ń dàná ní Ajọwa tẹ́lẹ̀, ọmọ mi 5 di

Òògùn Olóró Lílò lo ko ba mi

Lẹ́yìn tí to parí ilé ẹ̀kọ́ girama, Chidinma wọlé sí Fasiti Eko lati gboye ìmọ̀ ìròyìn

Chidinma ni lẹ́yìn tí òun wọ ilé ẹ̀kọ́ Unilag ni òun bẹ̀rẹ̀ síní mu sìgá.

Bákan náà lo fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé òun ni wọ́n rí nínú fọ́nran kan tó n jà ràinràin lórí ayélujára ti òun ń fa síga nígbà ti orin ń lọ lábẹ́lẹ̀.

Ọ̀dún díẹ̀ sẹ́yìn ni mo bẹ̀rẹ̀ sí ní fa sìgá, àwọn ọ̀rẹ́ mí ló kọ mi bí wọ́n ṣe n fa sìgá, sùgbọ́n èmi àti wọn kò jọ rin mọ́.

Chidinma ṣàlàyé pé, ko sí àlàyé mííràn tí òun tún lè sọ mọ́ ju pé ọ̀rẹ́ òun lásán ni Ataga, ti òun sì pàdé rẹ̀ ni nnkan bi osù mẹ́rin sẹ́yìn.

Àkọlé fídíò, Alhaja Rukayat Batimoluwasi Oniwaka: Orin Wákà la fi ń ṣe Wáàsí, o tó ọdún 70 tí mo tí bẹ̀

Ó fi kun pé, Ataga ko ti fi fótò mọ̀lẹ́bi rẹ̀ han oun rí àti pé, nígbà oun ri, ''nigba míràn, yóò ṣe bi ẹni pé kò tí ni ìyàwò, ìgbà mííràn sì rèé, á tún ṣe bí ẹni tí ó lẹbí.

Chidinma ni Ataga má ń mú òògùn olóró, ó sì maa n mu ọtí.

Àwọn ọlọ́pàá lọ́jọ́bọ ní àwọn ti fi bàbá Chidinma sílẹ̀ nítorí Chidinma ti sàlàyé pé bàbá òun kò mọ̀ sí ihuwasi oun, sùgbọ́n àwọn ọlọ́pàá ni àwọn mú bàbá náà nítórí ó sediwọ lati mú ọmọ rẹ̀.

Bákan náà ni wọ́n ti fí ẹni tó ni yàrá ti wọ́n yá lò náà sílẹ̀, Nkechi Mogbo nítori gbogbo ẹjọ ti Chidinma ro, kò fi Obinrin náà sínu iṣẹ́lẹ̀ náà.

Hakeem Odumosu ni àwọn sì ń tẹ̀síwájú nínú ìwádìí àwọn lori isẹlẹ yii.