Baba Ijesha: Femi Adebayo náà dá sí èdè àìyedè tó ń wáyé nínú TAMPAN

Femi Adebayo

Oríṣun àwòrán, femiadebayosalami/Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ẹgbẹ TAMPAN fi ikilọ ranṣẹ si Iyabo Ojo ati Nkechi Blessing pe ki wọn yeTe ba ẹgbẹ TAMPAN lorukọ jẹ kaakiri.

Gbajugbaja oṣere Nollywood, Femi Adebayo ti fi ero rẹ lede gẹgẹ bi ọmọ ẹgbẹ awọn oṣere ni Naijiria, TAMPAN, lori awuyewuye to n waye ninu ẹgbẹ naa.

Eyi ko ṣẹyin bi ẹgbẹ TAMPAN ṣe fofin de oṣerebinrin meji, Iyabo Ojo ati Nkechi Blessing lori ipa ti wọn ko lori ọrọ Baba Ijesha ti wọn fẹsun kan pe o ṣe aṣemaṣe pẹlu ọdọmọde kan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lasiko ti Femi Adebayo n fi ero rẹ han ninu fidio kan to gbe jade loju opo Instagram rẹ, o sọ wi pe ọrọ naa yoo loju tu laipẹ.

''Gẹgẹ bi ọmọ ẹgbẹ TAMPAN, mọ fẹ fi idi rẹ mulẹ pe ẹgbẹ naa ko ni fi ti ọrọ ẹnu abi irunu da ẹjọ kankan, amọ ẹgbẹ yoo ṣewadii finifini.''

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post

''Ikini ni pe ẹgbẹ TAMPAN ko ni fi aye gba iwa ọdaran tabi iwa ipa kankan ninu ẹgbẹ nitori ohun ti ofin ẹgbẹ dale lori ni ibọwọ fun ara ẹni ati ẹtọ.

Bakan naa ni o jẹ wa logun lati ri pe awọn ọmọ ẹgbẹ ni itẹsiwaju ninu iṣẹ ti wọn yan laayo, ki igbega le ba ẹka oṣere ni Naijiria.

Ikẹta nipe ẹgbẹ ko ni fi aye gba iwakiwa lati ọdọ ẹnikẹni, amọ ọrọ ti wọ inu ara wọn ninu iṣẹlẹ to waye naa.

Nitori naa, ijiroro ati ibaraẹnisọrọ ti bẹrẹ pẹlu gbogbo awọn ti iṣẹlẹ naa ta ba, a si ni igbagbọ wi pe ohun gbogbo yoo niyanju laipẹ.

Laipẹ yii ni ẹgbẹ TAMPAN fi ikilọ ranṣẹ si Iyabo Ojo ati Nkechi Blessing pe ki wọn ti ọwọ ọmọ wọn bọ aṣọ pẹlu bi wọn ṣe n ba ẹgbẹ TAMPAN lorukọ jẹ kaakiri.

Àkọlé fídíò, Glorious Twins: Taiwo àti Kehinde Ekundayo ní ọ̀dọ́ ìyá àgbà ní àwọn ti ẹ̀bún orin kíkọ

Bakan naa ni wọn le Blessing kuro ninu ẹgbẹ fun igba diẹ nitori o ba akẹgbẹ rẹ, Kehinde Adams ja lori ẹrọ ayelujara nitori ọrọ Baba Ijesha kan naa.

Amọ, ẹsun ti won fi kan Iyabo Ojo ni wi pe o sọrọ si awọn agba oṣere to dakẹ lori ọrọ Baba Ijesha, ti wọn si paṣẹ fun awọn oṣere lati maṣe lo Iyabo Ojo tabi Nkechi Blessing ninu fiimu ti wọn ba fẹ gbe jade.