Auxillary Kidnap Attempt: Akọ̀wé ẹgbẹ́ PMS ní àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ọhún ni kò jẹ́ kí wọ́n rí Auxilliary gbé lọ

Oríṣun àwòrán, Facebook/Auxilliary Nation
Akọwe agba fun ajọ to n ri si akoso awọn ibudokọ, Oyo Park Management System (PMS) nipinlẹ Oyo, Comrade Oluwatomiwa Omolewa ti sọrọ lori isẹlẹ kan to waye lọjọ Isẹgun lori alaga ajọ naa.
Omolewa sisọ loju rẹ pe awọn eeyan kan lo wa nidii bi wọn se fẹ ji alaga ajọ PMS, Alhaji Isiaka Lamidi, ti ọpọ mọ si Auxilliary gbe lọ lọjọ Iṣẹgun niluu Ibadan.
Omolewa ṣalaye fawọn akọroyin pe awọn ọmọ ẹgbẹ PMS ni ko jẹ kawọn eeyan ọhun ri Auxilliary gbe lọ ni ọọfisi wọn to wa ni adugbo Podo-New Garage nilu Ibadan
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Sunday Igboho ní digbí lòun wà lẹ́yìn Nnamdi Kanu àti ìdásílẹ̀ Biafra
- Eré wa ni kẹ wò, ẹ má wo aṣemáṣe àwa onítíátà - Olaiya Igwe
- Àwọn àgbà Yorùbá sọ̀rọ̀ lórí ìbẹ̀rù pé wọ́n le gbé Sunday Igboho lẹ́yìn tọ́wọ́ tẹ Nnamdi Kanu
- Èèmọ́ wọ̀lú, ta ló yìnbon pá Babalawo àti ẹlòmíì, tí ọ̀pọ̀ sì fara pa ní Ajaawa?
- Bíṣọ́ọ̀bù Enugu ní obìnrin ni wọ́n fi mú Nnamdi Kanu
- Ẹni tó bá tàbùkù àgbà níta, ti ń bú òbí rẹ̀ nílé tẹ́lẹ̀ - Yomi Fabiyi
Akọwe ẹgbẹ PMS ni awọn ọmọ ẹgbẹ naa lo gbe ija ko awọn to fẹ mu Auxilliary, nigba ti wọn sọ pe ọga agba ọlọpaa ni Naijiria lo paṣẹ pe kawọn wa mu eekan tẹlẹ ninu ẹgbẹ awakọ ero nipinlẹ Oyo naa.
''O tiẹ ya wa lẹnu pe ko si ọlọpaa kankan lati ipinlẹ Oyo ninu awọn to ni ọga ọlọpaa Naijiria lo ni kawọn wa mu Auxilliary wa.
A pada le wọn kuro lẹyin ti wọn ko le fi kaadi idanimọ wọn han pe lootọọ ọlọpaa ni awọn i ṣe,'' Omolewa lo sọ bẹẹ.
Nigba to n dahun ibeere lori boya bi wọn ṣe fẹ mu Auxilliary nii ohun ṣe pẹlu iṣẹlẹ ipaniyan to mu ẹmi Rahmon Azeez atawọn meji mii lọ ni Iwo Road laipẹ yii, Omolewa ni ko si ohun to jọ bẹẹ rara.

Oríṣun àwòrán, The park Management Oyo State/Facebook
O ni ''ileeṣẹ ọlọpaa ti mu awọn afurasi to ṣagbatẹru rogbodiyan ni ikorita Iwo Road naa, ko si ẹnikan ninu awọn afurasi naa ti wọn mu to sọ pe Auxilliary lo ran awọn niṣẹ.''
Akowe ẹgbẹ PMS ni gbogbo awọn to fẹ mu Auxilliary lọna aitọ ni yoo kuna, nitori ẹgbẹ naa ko ni ṣe ohun kan to tapa si ofin orilẹede Naijiria.
Igbiyanju wa lati gbọ tẹnu ileesẹ ọlọpaa nipa isẹlẹ yii ni ko seso rere nitori agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa ipnilẹ Oyo ko gbe ipe wa.
- Ọjọ́ mẹ́rin ni mo fi bẹ Princess pé kí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha má di ẹjọ́ - Iya Rainbow
- Ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ Interpol ṣèrànwọ́ fún ìjọba àpapọ̀ láti mú Nnamdi Kanu
- Orí àgbá ẹ̀tù láwọn èèyàn Ibarapa jókòó lé, wàhálà ń bọ̀ - OPC mẹ́ta tó gba ìdáǹdè
- Jide Kosoko, tí mo bá tú àṣírí rẹ, àwọn ọmọbìnrin rẹ yóò dọwọ́ bojú - Nkechi Blessing yarí


















