Nnamdi Kanu: Omoyele Sowore ní gbọin-gbọin lòun wà lẹ́yìn Nnamdi Kanu

Nnamdi Kanu laarin awọn ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lẹyin ti ijọba apapọ mu olori ẹgbẹ to n jijagbara fun idasilẹ orilẹede Biafra (IPOB), Nnamdi Kanu lọjọ Iṣẹgun, Biṣọọbu ijọ Anglican niluu Enugu, Ẹniọwọ Emmanuel Chukwuma ti sọ pe ipasẹ obinrin ni wọn fi mu.

Ẹniọwọ Chukwuma ni to salaye ọrọ yii fun iwe iroyin Punch, wa lu ijọba lọgọ ẹnu lori bi wọn ṣe mu Kanu pada, lẹyin to sa lọ tẹlẹ nigba ti wọn kọkọ fi ọwọ ofin mu un.

''Nigba to wa ni oke okun, oun lo n lo awọn ọmọ ẹgbẹ IPOB nilẹ Igbo lati maa da rogbodiyan silẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọpọ igba ni a kilọ fun un, ṣugbọn ko gbọ si wa lẹnu nigba naa.

Ohun ti awa ro ni pe gẹgẹ bi olori, o yẹ ki Kanu wa sile, ki a si jọ sọ asọyepọ lori ọrọ to wa nilẹ.

Àkọlé fídíò, #BBCNigeria2019: Nnamdi Kanu sọrọ lórí àwọn oludije PDP àti APC

Kanu ko sọwọ obinrin tawọn ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ dẹ si i lati ilu London lọ si orilẹede Brazil.

Eleyii fihan pe olori yẹpẹrẹ ni Kanu, bi bẹẹ kọ ọ, ba wo ni obinrin ṣe maa ri ẹ mu ti o ba jẹ olori gidi?

Obinrin lo tan Kanu lati ilu London lọ si orilẹede Brazil, ohun itiju nla ni.

Omoyele Sowore ni gbọin-gbọin lòun wà lẹ́yìn Nnamdi Kanu:

Ninu ọrọ tiẹ, Omoyele Sowore to ṣagbatẹru iwọde RevolutionNow ni gbọin gbọin loun wa lẹyin Kanu.

Sowore ni oun naa ti wa ni ipo ti Kanu wa lọwọ yii ri tẹlẹ.

O ni iru iriri ati idojukọ ti awọn ajijagbara maa n ri ni olori ẹgbẹ IPOB n ri lọwọ bayii.

Àkọlé fídíò, Glorious Twins: Taiwo àti Kehinde Ekundayo ní ọ̀dọ́ ìyá àgbà ní àwọn ti ẹ̀bún orin kíkọ

Asaaju Afenifere koro oju si bi ilẹ okeere se fa Kanu silẹ:

Eekan ẹgbẹ Afenifere, Oloye Ayo Adebanjo ti bu ẹnu atẹ lu bi ilẹ okeere ṣe fa Kanu le ijọba Naijiria lọwọ ni tẹ.

Oloye Adebanjo ni ko tọ ki wọn tun fa Kanu le ijọba Naijiria, to jẹ ọta rẹ lọwọ niwọn igba ti wọn ti gba a laaye lati ṣe atipo nibẹ tan.

Adebanjo ni ohun ti ijọba UK ṣe fun Kanu, wọn ti ṣe bẹẹ naa ri fun ẹgbẹ oṣelu Action Group, nigba ti wọn fa Oloye Anthony Enahoro le ijọba Naijiria lọwọ.

Ijọba Gẹẹsi ni ilẹ oun kọ ni wọn ti mu Nnamdi Kanu:

Amọ, ilẹ Gẹeṣi ti sọ pe UK kọ ni wọn ti mu Kanu pada gẹgẹ bi iroyin kan ṣe sọ.

Agbẹnusọ fun olu ileeṣẹ ijọba orilẹede UK ni Naijiria, Dean Hurlock, ṣalaye pe kii ṣe UK ni wọn ti mu Kanu ki wọn to da a pada si Naijiria.

IPOB ni eera ko gbọdọ rin Kanu ni ahamọ

Ẹwẹ, ẹgbẹ IPOB ti wa kilọ fun ijọba apapọ pe eera ko gbọdọ ra Kanu ni atimọle ajọ DSS to wa.

Ninu atẹjade to fi sita lọjọ Iṣẹgun, ẹgbẹ naa ni Kanu ko tii jẹbi ẹsun kankan labẹ ofin pẹlu gbogbo ẹsun ti wọn fi kan an.

Ẹgbẹ naa nkan ko gbọdọ ṣe e titi ti igbẹjọ rẹ yoo pari nitori ẹtọ rẹ ni lati wa ni alaafia bi igbẹjọ ṣe n lọ lọwọ.

Amin iyasọtọ kan
Nnamdi Kanu

Oríṣun àwòrán, SCREEN SHOT

Ilé ẹjọ́ ti pàṣẹ kí wọ́n fi Nnamdi Kanu sí àhámọ́ títí di ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù tó ń bọ̀

Ọwọ ijọba apapọ orilẹede Naijiria ti tẹ asaaju ikọ to n jija gbara fun ẹya Igbo, Nnamdi Kanu.

Minisita feto idajọ ati agbẹjọro agba ni Naijiria, Abubakar Malami lo fidi isẹlẹ naa mulẹ fawọn akọroyin lọjọ Isẹgun.

Malami ni wọn mu Kanu nilu Ọba to wa, ti wọn si gbe wa sorilẹede yii lọjọ Aiku.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O fikun pe ọwọ tẹ asaaju ajijagbara fun ikọ IPOB naa pẹlu ifọọwọsowọpọ awọn ileesẹ agbofinro lorilẹede Naijiria ati ajọ ọtẹlẹmuyẹ Interpol.

Nnamdi Kanu

Oríṣun àwòrán, Screen Shot

Bakan naa ni Minisita feto idajọ fikun pe wọn yoo gbe Kanu lọ sile ẹjọ giga tijọba apapọ nilu Abuja lati tẹsiwaju pẹlu ẹjọ to n jẹ tẹlẹ.

Awọn ẹsun naa lo nii se pẹlu iwa idunkoko mọ ni, idaluru, kiko ohun ija oloro jọ lai bofin mu ati akoso awujọ to tako ofin.

Bẹẹ ba gbagbe, osu Kẹrin ọdun 2017 ni wọn gba oniduro Kanu lori awijare pe ara ko da amọ to sa kuro lorilẹede yii.

Lẹyin eyi ni awọn ileesẹ agbofin nilẹ Naijiria kede pe awọn n wa olori ikọ ajijagbara ti ijọba fofin de naa.

Ki lo ti waye tẹlẹ:

Ile ẹjọ giga ilu Abuja lo pasẹ losu kẹta ọdun 2019 pe ki wọn lọ mu asaaju ikọ IPOB, Nnamdi Kanu.

Ẹsun idaluru ni wọn fi kan Kanu nigba naa, to si foju bale ẹjọ.

Àkọlé fídíò, Kunle Olajide, Akọ̀wé ìgbìmọ̀: Ẹ̀yin ọ̀dọ́, ọjọ́ ọ̀la yin kò ṣe e fọ́wọ́ ẹ sọ̀yà, ẹ díde

Adajọ Binta Nyako wa kede pe oun yoo maa tẹsiwaju pẹlu igbẹjọ Kanu bi o tilẹ jẹ pe o ti kuna lati yọju sile ẹjọ lati ọjọ Kẹẹdọgbọn osu Kẹrin ọdun 2017.

O ni Kanu ko salaye idi ti ko fi yọju sile ẹjọ rara, idi si ree to fi gbe idajọ rẹ le ofin ilẹ wa, abala iwa ọdaran tọdun 2015, ori 352, ẹsẹ kẹrin.

Amọ agbẹjọro fun Nnamdi Kanu, Ifeanyi Ejiofor lo tako ẹbẹ agbẹjọro fun ijọba, Magaji Labaran.

Ejiofor ni ki ile ẹjọ fun oun ni akoko diẹ si lati le salaye idi ti onibara oun ko fi yọju sile ẹjọ amọ ile ẹjọ faake kọri lati gba ẹbẹ rẹ.