White Witches Association: Ẹgbẹ́ àwọn àjẹ́ funfun ní àbò tó mẹ́hẹ lè fọ́ Nàíjíríà sí wẹ́wẹ́, ẹ̀jẹ̀ ti pọ̀jù

Oríṣun àwòrán, others
Ẹgbẹ awọn ajẹ funfun lorilẹede Naijiria, White Witches Association of Nigeria (WWAN) ti ṣekilọ pe o ṣeeṣe ki orilẹede Naijiria pin si mẹrin tabi mẹfa o.
Ẹyin naa mi kanlẹ lori ikede yii abi?
Awọn ajẹ funfun naa ni bi iṣẹlẹ ipaniyan lọtun losi se n waye latọwọ awọn agbesumọmi Boko Haram, atawọn agbebọn to n ṣọṣẹ kaakiri pẹlawọn darandaran Fulani, ko ba tete dopin, ọrọ lee bọ sori fun Naijiria.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Dino Melaye sọ̀rọ̀ sókè lórí ọ̀rọ̀ ìfẹ́ tí wọn ló ní pẹ̀lú àwọn òṣèrẹ tíátà
- Ẹgbẹ́ òṣèré tíátà, TAMPAN fọnmú mọ́ Iyabo Ojo àti Nkechi Blessing lọ́wọ́
- Bí ìlànà ìsìnkú TB Joshua yóò ṣe lọ rèé - Mọ̀lẹ́bí kéde
- Yomi Fabiyi fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí Iyabo Ojo lẹ́yìn béèlì Baba Ijesha
- Iyabo Ojo gbé fídíò míì síta nípa Olofana àti ìhùwàsí àwọn onítíátà lẹ́yìn béèlì Baba Ijesha
- Agbébọn jí Ọba alayé lọ lọ́nà oko l‘Ekiti, Olorì móríbọ́
- Olofa Ina tọrọ àforíjìn lọ̀wọ̀ àwọn òṣèré tíátà obìrin lórí ọ̀rọ̀ tó sọ níbi ìgbẹ́jọ́ Baba Ijesha
- "A ń sàárò ọgbọ́n ìṣèjọba àti òṣèlú tí Sẹ́nétọ̀ Abiola Ajimobi ni nígbà ayé rẹ̀"
- Àwọn agbébọn pa ìyàwò èèkàn olóṣèlú ní Ibadan, ọlọ́pàá ní adigunjalè ní wọ́n
Agbẹnusọ fun ẹgbẹ naa nigba kan ri, Dokita Iboi Okhue ṣalaye ninu ipade pẹlu awọn akọroyin lẹyin ipade awọn ajẹ naa to waye nipinlẹ Cross rivers ati Kaduna loṣu keji ati ikẹrin ọdun 2021, lo sisọ loju ọrọ naa.
Afojusun ipade naa ni lati wa ojutu si bi itajẹsilẹ ṣe pọ lorilẹede Naijiria, ti wọn si ni awọn ri aridaju rẹ pe, bi awọn alaṣẹ ko ba tete wa nnkan ṣe si eto aabo to mẹhẹ naa, o ṣeeṣe ki Naijiria o pin si wẹwẹ.
O ni ọrọ abo to mẹhẹ lorilẹede Naijiria bayii n kọ awọn ajẹ lominu bẹẹ ni gbogbo awọn majẹobajẹ lorilẹede Naijiria lo gbọdọ fọwọsowọpọ pẹlu Aarẹ Buhari nitori ajeje ọwọ kan ko lee gbe ẹru dori.














