Ghana Witches: Wò bí wọ́n ṣe pa ìyá ẹni ọdún 90 tí wọ́n pè ní àjẹ́

Iya ti wọn n ju okuta pa naa

Oríṣun àwòrán, facebook/ AFia pokua

Iya agba ẹni aadọrun ọdun kan, ni iya ooṣa kan atawọn aladugbo kan ti sọ lokuta pa lori ẹsun pe ajẹ ni.

Iya olooṣa yii fi ẹsun kan iya arugbo ọhun, ti orukọ rẹ n jẹ Akua Denteh pe ajẹ mujẹmujẹ ni.

Eyi lo si sun awọn ara adugbo lati dide si iya arugbo naa, wọn fi oniruuru iya jẹ ẹ titi to fi gbe ẹmi mi.

Ni ilu Kafaba, lagbegbe Salaga ni orilẹede Ghana ni iṣẹlẹ yii ti waye.

Fidio kan eyi to gbalẹ bi iso ẹwa lori ayelujara lo ṣafihan bi wọn ṣe yi iya arugbo naa ka, ti wọn si n lo awọn nnkan lati gba a lori.

Àkọlé fídíò, Africa Eye: Coronavirus di adákẹ́jà ní Somalia, ikú ọ̀wọ́ọ̀wọ́ ń peléke si

Wọn n digbaju luu, wọn yọ ẹgba ti i fun ọpọlọpọ igba, bi o ṣe joko sori ilẹ titi ti ẹlẹmi fi gba a.

Bawo lo ṣe ṣẹlẹ?

Iroyin sọ pe wọn gbe iya arugbo naa lọ si ile iya olooṣa ọhun.

Iya olooṣa naa pe awọn ayajọ kan, lo ba kede fun gbogbo awọn to wa nibẹ pe ajẹ ni iya arugbo naa.

Lẹyin eyi ni wọn ba din dundun iya fun iya agbalagba naa.

Lẹyin ọpọlọpọ lilu yii ni mama naa daku, ti wọn si fun un ni agbo kan mu ki wọn to gbe e lọ si ile rẹ nibi to ku si.

Àkọlé fídíò, Peters Ijagbemi dá àrá lórí ètò 'Ṣé o láyà' ti BBC Yorùbá lọ̀sẹ̀ yìí

Awọn ọlọpaa ti n wa awọn to ṣe ọṣẹ naa

Awọn ọlọpaa ti gbe oku iya agbalagba naa lọ si ile igboku pamọ si kan, ni ile iwosan nla Tamale Teaching Hospital fun ayẹwo.

Ni bayii, ọga agba ọlọpaa lorilẹede Ghana, James Oppong-Boanuh ti ran awọn agbofinro lọ si ẹkun naa lati lọ ṣawari iya olooṣa ọhun, atawọn araalu to pa obinrin naa.

Gẹgẹ bi ọlọpaa ṣe sọ, wọn n wa iya Hajia Filina to jẹ iya olooṣa naa, eeyan kan torukọ rẹ n jẹ Aliu to jẹ olukọ, Bumaye, Ashley ati Manafo, ti iroyin sọ pe wọn ti juba ehoro.

Ẹgbẹrun meji Cedi owo ilẹ Ghana ni wọn ti kede gẹgẹ bi ẹbun, fun ẹnikẹni to ba lee ran ọlọpaa lọwọ lati ṣawari wọn.