Baba Ijesha: Iyabo Ojo rí mí fín lórí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha, ó pa fóónú mọ́ mí lẹ́nù
Gbajugbaja Oṣere ni Naijiria, Deji Aderemi ti ọpọ eniyan mọ si Ọlọfaina ti bẹ Iyabo Ojo ati awọn miran ti ọrọ kan pe ki wọn dariji Baba Ijesha lori ọrọ ifipabanilopọ ti wọn fi kan an.
Olofaina sọ bẹẹ lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ ni ileẹjọ ti igbẹjọ Baba Ijesha tio waye ni Ọjọbọ.
O ni iru eyi ko ṣẹlẹ ri ni agbo oṣere ki wọn ma a gbe ara wọn lọ si ileẹjọ.
- Iná sọọ! Àwọn ọmọdé tó ń kọ́ ìjà ààbò ara ẹni "Kongfu jó ráúráú
- Ẹ gbà wa o! Ìwé ìrìnà àti ìwé ìgbélùú wa ní Oman ti "expire", wọ́n tún ní Nàìjíríà ti di ibi àìwọ̀
- Kí ló mú Olorì Badrat Ajoke kúrò ní ààfin Oyo lọ́jọ́ Iléyá?
- Ẹ̀yin ọmọ Yoruba, ẹ múra láti dìbò ''referendum'' kúrò ní Naijiria, ìjọ̀ba àpapọ̀ à ń bò- Banji Akintoye
- Mo nírètí pé Baba Ijẹsha yóò gba béèlì ní iléẹjọ́ tí yóò tí farahàn lónì - Yomi Fabiyi
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo àti àwọn ẹlẹ́sìn àbáláyé bẹ̀rẹ̀ àjọṣepọ̀ láti fí opin sí ìṣoro ètò aàbò
Gbajugbaja oṣere naa fikun wi pe igbiyanju oun lati ba Iyabo Ojo sọrọ lori iṣẹlẹ naa lo jasi pabo, to si sọ fun oun pe ki oun bọ silẹ nibẹ gẹgẹ bi esi to fun oun, ko to di wi pe o pa foonu mọ oun lẹnu.
Bakan naa ni lo fikun pe oun wa lati ilu Ede,nipinlẹ Osun wa si ileẹjọ lati le wo bi ọrọ naa ma jasi.
Ati wi pe ẹgbẹ ti ṣetan lati ba awọn ti ọrọ naa kan wi, amọ ki wọn parapọ jẹ ọkan.