Niger Delta Avengers: Buhari fèsì pé gbogbo ohun tí NDA ń bèèrè fún, ni òun ti ṣe

Muhammadu Buhari atawọn Niger Delta Avengers

Oríṣun àwòrán, AFP

Lẹyin ti wọn sinmi fun bi ọdun mẹta, awọn ajijagbara fun agbegbe Niger Delta, eyiun Niger Delta Avengers (NDA) tun ti gba ọna miran yọ bayii.

Lọtẹ yii, ẹgbẹ Avengers ti ṣe agbekalẹ eto ti wọn pe orukọ rẹ ni 'Operation Humble', eleyii ti wọn fi leri pe awọn yoo fi ba ọrọ aje Naijiria jẹ nipa biba awọn ileeṣẹ epo rọbi to wa lẹkun naa jẹ.

Ninu atẹjade kan ti ẹgbẹ ọhun ti fi sita ni wọn ti ṣalaye pe awọn ṣetan lati ri pe ọrọ aje Naijiria dẹnu kọlẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Koda wọn tun leri pe awọn ṣetan lati da ṣẹria fawọn oloṣelu to n gbimọ pọ pẹlu ijọba apapọ lati fi ẹtọ awọn eeyan ẹkun Niger Delta dun wọn.

Eleyii ṣẹlẹ lẹyin oṣu kan ti olori awọn ajijagbara Niger Delta kan, Ekpemupolo, ti ọpọ mọ si Tompolo, kọ iwe ranṣẹ si ijọba apapọ lati ṣe ifilọlẹ igbimọ to n ri si ọrọ Niger Delta.

Àkọlé fídíò, Olowo: Bí ìjọba bá ṣe àtúntò tún yẹ, Sunday Igboho yóò fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú wọn

Tompolo sọ ninu lẹta naa pe ti ijọba ko ba ṣe bẹẹ, awọn ṣetan lati ba awọn ileeṣẹ ifọpo Naijiria to wa lẹkun naa jẹ.

Ọjọ meje pere ni Tompolo fun ijọba lati gbe igbesẹ lọri ọrọ naa.

Ẹgbẹ NDA tun sọ ninu atẹjade to fi sita pe, oun ti sọ fawọn ajijagbara lati pada si inu igbo tawọn irinṣẹ ifọpo wa lẹkun naa.

Buhari fesi pada fawọn Niger Delta Avengers

Ẹwẹ, ijọba apapọ ti fesi si ileri awọn ajijagbara Niger Delta Avengers, wọn ni ko si ọrọ ninu ohun ti ẹgbẹ naa n sọ rara.

Ijọba ni gbogbo ohun ti ẹgbẹ naa n beere fun, ni ijọba ti ṣiṣẹ lori rẹ.

Ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ aarẹ fi sita nipasẹ oludamọran fun Aarẹ Muhammadu Buhari lori ọrọ iroyin, Femi Adesina, ijọba ni o jẹ iyalẹnu pe ẹgbẹ NDA n dunkoko mọ ijọba lẹyin ti Buhari ti gbe igbesẹ lori ọpọ ohun ti wọn n beere fun.

Adesina ṣalaye pe ijọba Buhari ti gbe igbesẹ lori atunto ijọba ati idagbasoke ẹkun Niger Delta ti ẹgbẹ NDA n sọ nipa rẹ.

Adesina sọ ninu atẹjade naa pe, Aarẹ Buhari ti ṣepade pọ pẹlu awọn alaṣẹ ẹkun Niger Delta ati ẹgbẹ Ijaw, Ijaw National Congress (INC).