Oduduwa Nation: Àwọn obìnrin náà ní alálẹ̀ ló rán àwọn wa sílé lórí bí Yorùbá yóò ṣe dá dúró

Oríṣun àwòrán, Ooni Adeyeye Enitan Ogunwusi, Ojaja ll Facebook
Agbarijọpọ àwọn obinrin to jẹ ọmọ Yoruba to wa nilẹ okeere ti ṣabẹwo si aafin Ooni ti Ife, Ọba Adeyeye Ogunwusi, lati beere fun ipinnu to fẹṣẹ mulẹ.
Awọn obinrin ọhun ti iroyin sọ pe wọn to ẹgbẹrun kan niye, lo wa lati orilẹ-ede mẹtadinlogoji.
Alànà fun ìlànà Ọmọ Oodua, Ọjọgbọn Banji Akintoye si lo lewaju wọn lọ si aafin Ooni.
- Kábíyèsí Ooni ti forí jin Sunday Igboho lẹ́yìn tó túúbá- Ààfin Ile Ife
- Sunday Igboho ṣọ́ra ṣe, jẹ́ kí Seyi Makinde ṣiṣẹ́ tí òfin gbé le lọ́wọ́ - Ooni Ife
- Orí mi wú báwọn oríadé ṣe ní kò sí ààyè mọ́ láfi fi ọmọ Yorùbá ṣètùtù Nàìjíríà - Sunday Igboho
- Femi Fani-Kayode sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí Tinubu tori kò dìde kí Ooni
- Drone àti CCTV ni yóò máa ṣọ́ ọ̀pọ̀ igbó tó wà nílẹ̀ Yorùbá - Ooni
- Ooni Ife fohùn ránṣẹ́ sí Boris Johnson, ó ní, "bóo bá joun gbé, má johùn gbé"
- Kí nìdí tí Ooni Adeyeye Ogunwusi fi gbé Àrẹ̀mọ ilẹ̀ Oodua wọ ṣọ́ọ̀ṣì?
- Kà nípa ibi tí wọ́n bí Àrẹ̀mọ tuntun Ọọ̀ni Ife sí, àti orúkọ tó ń jẹ́
- Ooni Ile ife ṣàlàyé ohun tí Tinubu níló fún ilépa ipò ààrẹ lọ́dún 2023
Akọwe ikede fun Ọjọgbọn Akintoye, Maxwell Adeleye sọ ninu atẹjade kan pe, lọjọ Aiku ni awọn obinrin naa wa lati orilẹ-ede Amẹrika, Canada, Argentina, UK, Spain, ati awọn orilẹ-ede míì, lati bẹ Ooni wo.
Oludari awọn obinrin naa l'agbaye, Ọmọọbabinrin Simisade Kuku-Onayemi ati Akọwe rẹ, Dokita Owowunmi Babalola-Okocha lo lewaju wọn.

Oríṣun àwòrán, Ooni Adeyeye Enitan Ogunwusi, Ojaja ll Facebook
Awọn obinrin naa ni àwọn Alaalẹ ilẹ Yoruba lo sọ pe dandan ni ki awọn rin irinajo ẹ̀mí, ti yoo mu ki idasilẹ orilẹ-ede Oduduwa tete waye, lai si itajẹsilẹ.
Wọn ni nkan to mu awọn wa si ilẹ baba awọn niyii.
Kuku-Onayemi sọ pe, "gbogbo àwọn to wa fun àbẹ̀wò naa lo ri taje ṣe, sugbọn bi nkan ṣe ri nilẹ baba wa ko dun mọ wa ninu.
Nitori naa la ṣe wá, láti wa ọna abayọ ni ilana abalaye."

Ọ̀pọ̀ Yorùbá kò fẹ́ àtúntò mọ́, wọ́n fẹ́ ká dá dúró ni, èrò tèmi nìkan kọ́ - Gani Adams

Oríṣun àwòrán, Facebook/Seyi Makinde
Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba sọ pe pupọ ọmọ ilẹ Yoruba lo ti ṣetan, to si faramọ dida ijọba orilẹede ara wọn ṣe.
Gani Adams fidi ọrọ yii mulẹ nibi ifilọlẹ iwe kan to waye nilu Eko l‘Ọjọru
Agba ilẹ Yoruba naa ni oun faramọ ero ọkan awọn eeyan to sọ pe, ipinu Yoruba ti sun kuro nibi ki atunto iṣejọba waye nikan, si eyi to gbagbọ pe ki wọn maa da ijọba ilẹ wọn ṣe.
''Nkan tawọn olori Yoruba n beere ree, ti atunto ko ba waye ni Naijiria laarin ọdun mẹta si akoko yii, ọjọ iwaju ko le sunwọn.
Orisirisi atunto lo wa, o si yẹ ki wọn mọ iru eleyi taa n fẹ''
Iba tun sọ pe ti Naijiria yoo ba ṣe atunto, o yẹ ki wọn kẹkọ lara nkan to waye laarin ọdun 1960 si 1963, eyi to faaye gba ki ẹkun kọọkan maa mojuto idagbasoke ara rẹ.
O ni koda nigba aye ijọba ologun ọgagun Sani Abacha, igbalaaye wa labẹ ofin pe ki ẹkun mẹfẹẹfa lorileede Naijira maa ṣeto ara wọn niwọn bi aaye ba ṣe gba wọn.
''Ohun temi n fẹ ni iṣejọba awarawa. A o si gbaradi fun idunadura eyikeyi to ba waye''

Oríṣun àwòrán, Facebook/Seyi Makinde
Lẹnu ọjọ mẹta yii, awọn olori ati aṣaaju ilẹ Yoruba ti n tẹnu mọ atunto iṣejọba eleyi ti yoo gba agbara kuro lọdọ ijọba apapọ, ti yoo si faaye silẹ fun ẹkun kọọkan lati ṣeto ara wọn.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ọ̀gá iléèwé mẹ́ta wọ gàù lọ́dọ̀ ìjọba Ọsun torí ìpolongo ìdásílẹ̀ orílẹ̀-èdè Odùduwà
- Ọ̀fọ̀ ńlá ṣẹ̀! Iná sọ níléèwé, yàrá ìkàwé 22 jóná, akẹ́ẹ̀kọ́ 20 dèrò ọ̀run
- Á fojú Sunday Igboho balé ẹjọ́, á sì gba ₦500m owó ìtanràn fún Seriki - Ẹgbẹ́ Fulani
- Yorùbá sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí Arewa lórí bó ṣe fẹ́ àtúntò Nàíjíríà àmọ́ tó tako pínpín ipò ààrẹ
- Ọ̀rọ̀ agọ̀ ni Dambazau sọ bó ṣe fi OPC wé Boko Haram - Àgbààgbà Yorùbá
- Ẹ̀ẹ̀mẹrin ni ọ̀dá owó já mi kulẹ̀ lásìkò tí mo fẹ́ wọ Fáṣítì - Biola Adebayo
- Kí ló pa òkú mẹ́jọ tí wọ́n bẹ́ lórí ní Calabar?
Nibi ayẹyẹ taa n wi yi, aṣoju Ooni Ifẹ, iyẹn alara ti ilu Oodaye Ifẹ, Oba Segun Layade sọ pe, pupọ awọn alumọni ẹkun iwọ oorun guusu, lawọn eeyan ariwa n jẹ anfaani rẹ.
Oun naa wa pe fun idapada kikọ ẹkọ nipa itan lawọn ileẹkọ Naijiria .
Bode George to jẹ eekan ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, ti ọjọgbọn Charles Akitoye ṣoju fun naa sọ pe, eto iṣejọba Naijiria bo ti ṣe wa, ti yiwọ pupọ ati wi pe, eto ọrọ aje Naijiria fi sapa kan.


















