Biola Adebayo: Oríṣiríṣi ọjà ni mo kiri ní kékeré, síbẹ̀ mí ò rí owó wọ Fáṣítì

Oríṣun àwòrán, biolabayo1/Instagram
Yoruba bọ, wọn ni oju kii pọ́n iṣin ko ma là, bi ẹkun si pẹ titi di alẹ kan, ayọ n bọ ni owurọ.
Bẹẹ gan-an ni ọrọ ri fun gbajugbaja oṣerebinrin, Biola Adebayo nigba to n seranti ọpọ ipenija to la kọja, ko to jẹ eeyan nile aye.
Osere naa to ranti igbe aye rẹ àtẹ̀yìnwá gẹgẹ bi ọmọ atẹrọ̀fọ̀ dide ni orisirisi nkan ni oun kiri bii ọja lasiko ijagudu lati se rere nile aye.
- Toyosi Adesanya yarí lórí ọ̀rọ̀ Foluke Daramola
- Kí ló mú omijé jáde lójú Lateef Adedimeji?
- Obìnrin ẹlẹ́sẹ̀ kan tó ń kirí omi rí àánú gbà lọ́wọ́ ìjọba Eko
- ''Ẹ gbà mí o, ọkọ mí ti lé mi nílé torí mo ya ‘tatoo’ Tinubu sára''
- Ó ti tó àsìkò kí Nollywood fòpin sí èré ilé babaláwo lílọ - Clarion Chukwura
- Bidemi Kosọkọ di ìyá ìkókó
Aworan kan ti Biola fi si ori ayelujara Instagram rẹ, lo mu ko ranti awọn asiko ti nkan nira fun nigba ewe rẹ.
Ninu aworan naa, to ya nibi kan to ti n ṣe eré ti a o ti i mọ orúkọ rẹ, ni Biola ti n kiri búrẹ́dì.

Oríṣun àwòrán, biolabayo1/Instagram
O ni "aworan yii mu mi ranti igbe aye mi ni ibẹrẹ pẹpẹ. Oriṣiriṣi nkan ni mo kiri gẹgẹ bi ọdọmọbinrin, sugbọn búrẹ́dì tita ni awọn eeyan fi mọ òun.
O ni oun kiri burẹdi naa titi di igba ti oun di ọlọmọge ni, to si gba oun to ọdún meje, ki oun to wọ fasiti.
Ko tan sibẹ o, arẹwà oṣerebinrin naa to ti lami-laaka ninu iṣẹ sinima ṣíṣe sọ pe ẹẹmẹrin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni oun ni anfaani lati kekọọ ni fasiti, sugbọn ìṣòro aisi owo ja oun kulẹ.
Biola Adebayo to dupẹ lọwọ Ọlọ́run fun ibi ti igbeaye rẹ duro de bayii sọ pe kii ṣe iwe ẹ̀rí akọkọ nikan ni oun ni, o ni oun tun ti gba iwe ẹri 'masters' keji.
"Asiko naa kii ṣe nkan to rọrùn rara, àmọ́ mi o ti itori rẹ má nifẹ Ọlọ́run, bẹ ẹ ni mo si ni ireti. Ki n ma parọ, Ọlọ́run dára si mi lọpọlọpọ."
O fikun ọrọ rẹ pe, lootọ òun ko ti i de ipele to wu oun, àmọ́ oun ko si ni ipele ti oun wa tẹlẹ mọ.
Biola sọ pe gbogbo ẹpisteli ọrọ ti oun kọ waye lati le ṣe iwuri fun awọn eeyan pe, ki wọn o ma ṣe sọ ireti nu.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Gani Adams yarí pé èdè Yorùbá gbọdọ̀ di ọ̀rànyàn nílé ẹ̀kọ́ alákọ́bẹ̀rẹ̀
- Báwo ní Nàíjíríà ṣe ná $30m fún ààbò akẹ́kọ̀ọ́ lẹ́yin ìjínigbé akẹ́kọ̀ọ́ Chibok?
- Òjòóró ló wáyé lásìkò ìbò PDP l‘Osogbo - Fayose
- ''Ẹ gbà mí o, ọkọ mí ti lé mi nílé torí mo ya ‘tatoo’ Tinubu sára''
- Toyosi Adesanya yarí lórí ọ̀rọ̀ Foluke Daramola
- Kí ló mú omijé jáde lójú Lateef Adedimeji?
- Nǹkan ṣe mí! Mo jẹ àmàlà àti Fúrá papọ̀ láti sọ Yorùbá àtí Fulaní di ọ̀kan - Shehu Sani
- Obìnrin ẹlẹ́sẹ̀ kan tó ń kirí omi rí àánú gbà lọ́wọ́ ìjọba Eko
- Twitter gbé olú ilé iṣẹ́ rẹ̀ àkọ́kọ́ ní Áfíríkà lọ Ghana, ọmọ Nàíjíríà yarí
- Àlàyé rèé lórí ikú tó pa ọmọ Ronke Oshodi Oke
" Ohunkóhun to wu ki o ma a la kọjá, ma sọ ireti nu lori ilepa rẹ. O ni idi ti o fi n la asiko naa kọjá.
"Ìwọ ṣa ma a gbadura, fi Ọlọ́run ṣáájú, ja fafa, tẹra mọ isẹ rẹ, ki o si ni afojusun. Imọlẹ rẹ yoo tàn laipẹ.



















