Chibok Girls: Lẹ́yìn ọdún méje tí wọn gbé àwọn akẹ́kọ̀ọ́, owó ààbò fún iléèwé wọlẹ̀

Oríṣun àwòrán, AFP
Lasiko ijinigbe akẹkọọ ọlọpọ yanturu to waye lọdun 2014 ni Chibok, tii ṣe ọdún meje sẹyin, ìjọba ilẹ gẹẹsi ṣe agbekalẹ ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu dọla pẹlu atilẹyin asoju ijọba ilẹ gẹẹsi nigba naa, lati daabo bo awọn akẹkọọ nile iwe.
Baalu lo balẹ bagẹ silu Chibok ninu oṣu kẹta ọdun 2015, Okonjo Iweala tó jẹ mínísítà ètò ìsúna àti olori ajọ eleto katakara WTO báyii, lo bọ silẹ ninu baalu ọhun.
Ọpọ awọn obi ti wọn ji ọmọ wọn gbe ati awọ olori ilu si n duro wamuwamu lati kii kabọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Gani Adams yarí pé èdè Yorùbá gbọdọ̀ di ọ̀rànyàn nílé ẹ̀kọ́ alákọ́bẹ̀rẹ̀
- Òjòóró ló wáyé lásìkò ìbò PDP l‘Osogbo - Fayose
- ''Ẹ gbà mí o, ọkọ mí ti lé mi nílé torí mo ya ‘tatoo’ Tinubu sára''
- Toyosi Adesanya yarí lórí ọ̀rọ̀ Foluke Daramola
- Kí ló mú omijé jáde lójú Lateef Adedimeji?
- Nǹkan ṣe mí! Mo jẹ àmàlà àti Fúrá papọ̀ láti sọ Yorùbá àtí Fulaní di ọ̀kan - Shehu Sani
- Obìnrin ẹlẹ́sẹ̀ kan tó ń kirí omi rí àánú gbà lọ́wọ́ ìjọba Eko
- Twitter gbé olú ilé iṣẹ́ rẹ̀ àkọ́kọ́ ní Áfíríkà lọ Ghana, ọmọ Nàíjíríà yarí
- Àlàyé rèé lórí ikú tó pa ọmọ Ronke Oshodi Oke
O lọ si Chibok lati ṣe agbekalẹ okuta akọkọ fun atunṣe awọn ile ẹkọ ijọba ti awọn Boko Haram ti bajẹ lálẹ́ ọjọ buruku eṣu gbomin mu naa, tii se ọjọ kẹrinla, oṣu kẹrin ọdun 2014.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Abẹwo Okonjo Iweala yii jẹ ọkan lara igbesẹ to waye, lẹyin ti awọn ijọba ilẹ okere da si ọrọ ijinigbe awọn ọmọ to din diẹ ni ọọdunrun (276) lati ọwọ awọn agbesumọmí alakatakiti ẹsin ni Chibok lọdun 2014.
Ọpọ awọn ilu ati orilẹede lo n lo 'hastag' #BringBackOurGirls, ti olori ijọba ilẹ gẹẹsi tẹlẹri, Gordon Brown si ṣe agbatẹru ikowojọ ọgbọn milọnu dọla.
Owo ọhun si to bi mílọnu mejilelogun pọun fun aabo awọn akẹkọọ nile iwe, awọn ajọ kan labẹ isọkan agbaye, ijọba Naijiria ati awọn aladani kan, lo pese owo naa.
"Ẹẹdẹgbẹta ile iwe ni a o daabo bo: awọn yara ikẹkọọ tuntun yoo wa; a o mọ odi yi ile iwe ka, bakan naa ni a o gba awọn ọlọdẹ.

Oríṣun àwòrán, Borno state govenment
Erongba wọn ni pe, awọn akẹkọọ ko ni ni ifọkanbalẹ nikan ti wọn ba n lọ si ile ẹkọ, sugbọn ayika to duro re lati le kọ ẹkọ ati lati ni idagbasoke yoo wa" gẹgẹ bi Gordon Brown ṣe sọ ninu oṣu karun ọdun 2014
Mọrain-mọrain lọrọ naa dun lẹnu rẹ, ọdun meje ree, ko si aabo nile iwe ẹẹdẹgbẹta, wọn ko kọ kilaasi tuntun miran.
Titipa ni ile ẹkọ Chibok si wa
Saaju ni awọn aṣeyọri kan wa, bi wọn ṣe ṣe agbekalẹ awọn kilaasi fun awọn akẹkọ nibudo awọn ti ko ri ile gbe nitori ogun Boko haram.
Bakan naa ni wọn pese nkan ikawe fun awọn ọmọ, sugbọn ko ju ọdun meji lọ ti gbogbo eto yii fi doju de pẹlu ipolongo iside rẹ to waye nilu Abuja.
Awọn iṣẹlẹ ijinigbe ni awọn ile ẹkọ ni iha ariwa laipẹ yii fihan bi ijóba Naijiria ṣe kuna lati gbe awọn eto ijọba to le daabo bo awọn akẹkọọ nile iwe.

Titi di oni, ọmọ to din diẹ ni aadọfa lo sì wa ni ahamọ Boko haram lara awọn ti wọn ji ko ni Chibok.
Bakan naa, ọgbọn ninu awọn ile ẹkọ ti wọn pinu lati kọkọ fi bẹrẹ aabo nile ẹkọ, ni wọn ko tun kọ titi di oni yii.
Bo tilẹ jẹ pé, wọn kọ awọn kilaasi kọọkan lẹyin ti Ngozi Okonjo-Iweala ṣe abẹwo si Chibok, sùgbọ́n awọn adari ilu naa ni wọn ko kọ daadaa.
"Iṣẹ ajanbaku ni, gbogbo atẹgun to ba ti fẹ bayii, lo n ba apakan tabi omiran ile naa jẹ. Ojoojumọ lo n wo titi di oni yii, ko si ẹni to lo kilaasi naa."
Allan Manasseh agbẹnusọ ilu Chibok lo sọ bẹẹ fun BBC.
Ẹwẹ, àwọn ọmọogun lo n kọ kilaasi to wa nibẹ bayìí pẹlu iranlọwọ ijọba ipinlẹ Borno, lẹyin ti Gomina Babagana Zulum ṣabẹwo si ile iwe naa ni oṣu kọkanla ọdun to kọja, ti nkan to foju ri si ba a lọkan jẹ.

Ijọba n fi nkan falẹ
Ọgbẹni Brown, tii se asoju eto ẹkọ ninu ajọ isọkan agbaye sọ fun BBC ninu atẹjade kan pe, pẹlu gbogbo ijinigbe to tun waye yii, oun ti ṣe ipade pẹlu mínísíta ètò isuna Naijiria ni ọdun 2020.
O ni afojusun ipade naa ni lati gbiyanju, ko gbaruku ti eto idaabo to peye fawọn ile ẹkọ.
Titi di asiko yii, ofiisi rẹ ko dahun ibeere bi wọn ṣe na ọgbọn miliọnu dọla ti wọn ko jọ lọjọsi, nítori gbogbo owo naa, ijọba Naijiria ni wọn ko fun.

Oríṣun àwòrán, Ijoba ipinle Borno
Ètò ẹkọ girama agba, onikilaasi kinni (SSI) kuna ni ọdun 2016, eyiun ọdun kan lẹyin ti íjọba ana kuro lori oye ni Naijiria.
Goodluck Jonathan lo wa nijọba nigba ti wọn ji awọn ọmọ naa gbe, ti wọ́n si ṣe agbekalẹ eto ẹkọ SSI sùgbọ́n ààrẹ Muhammadu Buhari gba ijọba lọwọ rẹ.
Ajọ isọkan agbaye ati awọn miran to fẹ ṣe agbekalẹ owo sọ pe, ìjọba Naijiria kii yọju si ipade deede ati pe, awọn eto iṣejọba aarẹ Buhari di ọpọ nkan lọwọ, ti wọ́n si pada yọ ipese owo naa kúro ninu eto wọn.
Ninu atẹjade kan lati ile iṣẹ ilẹ gẹẹsi, o di ẹbi ru ijọba aarẹ Buhari pe oun ló fi nkan falẹ lati tẹle eto aabo fun ile ẹkọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images














