Akẹ́kọ̀bìnrin Chibok kan tó ráàyè sálọ kàwé gboyè l'Amẹrika

Awọn Chibok

Oríṣun àwòrán, PIUS UTOMI EKPEI

Ọkan lara awọn akẹkọbinrin Chibok to bẹ silẹ ninu ọkọ lati jajabọ lọwọ ikọ agbasunmọmi Boko Haram ti kẹkọ jade ni ileewe kan l'Amẹrika.

O kẹkọ jade nileewe Northern Virginia Community College lẹyin ọdun maarun, oṣu kan ati ọjọ mẹta ti Boko Haram ji awọn akẹkọbinrin to le ni igba gbe ni ilu Chibok.

Palmatah Mutah, ẹni ọdun mẹtalelogun, to bẹ silẹ ninu ọkọ lasiko ti wọn n gbe awọn akẹkọbinrin naa lọ, ni akẹkọọbinrin Chibok akọkọ to kẹkọ gboye imọ ijinlẹ akọkọ nilẹ okeere.

Lasiko ti ijinigbe naa waye, ọpọ ọmọ Naijiria ni ẹnu ya pe pupọ ninu awọn akẹkọ mẹtadinlọgọta to raaye salọ ko le sọ ede Gẹẹsi botilẹjẹ wi pe ipele to kẹhin ni wọn wa nileewe girama.

Ṣugbọn, Palmatah ti fihan pe oun yatọ si awọn to kù, pẹlu bo 'se ṣaṣeyọri ninu idanwo aṣewọle sileewe giga nilẹ okeere.

Awọn Chibok

Oríṣun àwòrán, PIUS UTOMI EKPEI

Oun nikan ṣi lo ti i raaye wọ ileewe giga Community College lai pe ọdun akọkọ to de Amẹrika, laarin awọn akẹkọbinrin Chibok mẹwaa ti agbẹjọro kan to jẹ ajafẹtọ ọmọniyan l'agbaye, Emaanuel Ogebe, ran lọ sileewe nilẹ okeere.

L'oṣu Kinni ọdun 2016, ni Palmatah ati awọn akẹkọọ meji mi i to bọ lọwọ Boko Haram, bẹrẹ eto ẹkọ wọn ni ileewe Community College kan ni Washington.

Awọn akẹẹgbẹ rẹ nigba kan to le ni ọgọrun lo ṣi wa ni ihamọ Boko Haram.