Chibok Girls: Jonathan n'írọ́ ni Cameron pa pé òun kọ ìrànwọ́ láti dóòlà àwọn akẹ́ẹ̀kọ́ Chibok

David Cameron ati Goodluck Jonathan

Oríṣun àwòrán, Facebook/Goodlucj Jonathan

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Olootu ijọba ilẹ Geẹṣi tẹlẹ ri, David Cameron, irọ nla lo pa mọ mio. Aarẹ ana orilẹede Naijiria, Goodluck Ebele Jonathan lo sọ bẹẹ.

Ọgbẹni Cameron lo kọ ninu iwe rẹ, to pe akọle rẹ''For the Record pe ijọba Naijiria labẹ akoso Aarẹ Jonathan kọ eti ikun si imọran lati ṣeranwọ fun Naijiria lati doola ẹmi awọn akẹẹkọbinrin ileewe Chibok tawọn ẹgbẹ agbesunmọmi Boko Haram jigbe lọjọ kẹrinla oṣu kẹrin ọdun 2014.

Skip Facebook post, 2

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post, 2

Aarẹ ana orilẹede Naijiria, Jonathan ninu esi rẹ lọjọ Abamẹta sọ pe o ba oun lọkan jẹ pe Ọgbẹni Cameron le sọ iru ọrọ bayii nitori ko si ohun to jọ bẹẹ rara.

Jonathan ṣalaye pe oun kọwe iranwọ gẹgẹ aarẹ Naijiria nigba naa si Cameron, ati si Aarẹ ilẹ Amẹrika nigba naa, Barrack Obama Amẹrika pẹlu Aarẹ ilẹ Faranse, François Hollande ati olootu ijọ orilẹde Israel, Benjamin Netanyahu lasiko naa.

Jonathan sọ pe ko mu ọpọlọpọ dani pe oun toun kọ iwe iranwọ naa lo wa tun sọ pe oun ko nilo iranwọ lati ilẹ okere.

Aarẹ orilẹde Naijiria tẹlẹ ri tun sọ pe oun loun fọwọ si ki awọn ọmọ-ogun ilẹ Gẹẹsi pẹlu atilẹyin awọn ọmọ ogun bẹrẹ iṣẹ lati doola ọmọ ilẹ Gẹẹsi kan, Ọgbẹni Chris McManus ati ọmọ ilẹ Italy kan, Franco Lamolinara tawọn Boko Haram ji gbe.

Jonathan tun ṣalaye siwaju pe ijọba ilẹ Gẹẹsi labẹ aṣẹ olootu Theresa May lọjọ kẹjọ oṣu kẹta ọdun 2018 naa jẹri si wi pe ko si otititọ kan ninu ọrọ ti Cameron sọ yii.