Xenophobia: Nàìjíríà àti South Africa ṣèpàdé lórí ìwé ìrìnà arìnrìnàjò

Oríṣun àwòrán, @BashirAhmad
Orilẹede Naijiria ati South Africa ti jọ forikori wọn si ti pa ohun pọ lati maa fun awọn oniṣowo, akẹkọọ atawọn to maa n rinrin ajo daadaa ni iwe irina ọlọdun mẹwaa.
Orilẹede mejeji yii fohun sọkan lori eyi lẹyin aṣeyọri ipade irẹpọ ti wọn jọ ṣe ni Pretoria, orilẹede South Africa.
Ninu iroyin ti a gbọ, aarẹ Muhammadu Buhari ati aarẹ Cyril Ramaphosa ni wọn jẹ jẹ alaga ipade naa nibi ti wọn ti gbe igbesẹ ọhun.
Ijọba ni idi ti wọn fi gbe igbesẹ yii lati ṣe moriya fun ibagsepọ alafia laarin awọn ọmọ orilẹede mejeji ati lati mu idagbasoke ba igbe aye, ọrọ aje ati oṣelu daadaa.
Bakan naa lasiko ipade yii, awọn aarẹ mejeji fimọṣọkan lati tete ṣe ikilọ lori iwa ipa ati didẹyẹ sira ẹni dipo bẹẹ wọn ni ibaṣepọ ati abo lawọn n wa.
Lafikun ohun to jẹyọ nibi ipade laarin orilẹede mejeji ni ṣiṣe agbekalẹ eto ti yoo mu ibaṣepọ orilẹede mejeji dan mọran sii nipa ṣiṣe ipade loorekoore bii ẹẹmeji lọdun lati sọrọ lori alafia awọn araalu mejeji.

Oríṣun àwòrán, @BashirAhmad
Nigbẹyin gbogbo gbogbo, minisita ti orilẹede Naijiria fun ọrọ ilẹ okere ati minisita orilẹede South Africa fun ọrọ ibaṣepọ agbaye, Ọmọwe Naledi Pandor jọ buwọlu akọsilẹ ipade naa eyi to jẹ ẹlẹẹkẹsan ipade apero ajọ ọlọrẹsọrẹ laarin orilẹede meji.











