Xenophobia: Àbọ̀ ààrẹ Muhammadu Buhari rèé láti ilẹ̀ South Africa

Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Twitter/Bashir Ahmad

Aarẹ Muhammadu Buhari ti pada si olu ilu orilẹede Naijiria, Abuja lọjọ Ẹti lẹyin abẹwo ọlọjọ meji si orilẹede South Africa.

Aarẹ Buhari ṣe oniruuru ipade pẹlu aarẹ ilẹ South Africa, Cyril Ramaphosa lori ibaṣepọ laarin awọn orilẹede mejeeji.

Ikọlu awọn ọmọ Naijiria laipẹ yii jẹ ọka gbogii ninu ọrọ tawọn olori orilẹede mejeeji jọ sọ.

Aarẹ Buhari fi aidunnu rẹ si bi awọn ọmọ South Africa ti fiya jẹ awọn ọmọ Naijiria ti wọn n ṣe atipo lorilẹede South Africa.

Aarẹ Ramaphosa tọrọ aforiji lọwọ Aarẹ Buhari lori bi awọn ọmọ South Africa ti ba ọpọ dukia awọn ọmọ Naijiria jẹ ninu ikọlu ọhun.

Muhanmadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Twitter/Bashir Ahmad

Mahammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Twitter/Bashir Ahmad

Ẹwẹ, ile iṣẹ ọkọ ofurufu Air Peace ti ko awọn Naijiria bi igba meji pada sile lẹyin iṣẹlẹ ikorira alejo to waye ni South Africa.