Imam Abubakar: ìdí tí mi ò fi fi méní pe méjì láti ṣí Mọ́sálásí fáwọn Krìstẹ́nì
"Lẹ́yìn ìrun, ló ṣẹlẹ̀, a ṣí Mọ́sálásí fún àwọn Krìstẹ́nì láti sá pamọ́".
Akọroyin BBC ba Imam Abubakar to gba awọn ẹlẹsin Kristẹni lalejo labule Ngargerwa, ipinlẹ Jos.
Imam ni oun ko la ala iru ayẹsi ti oun n ri gba bayii ri laye oun bẹẹ si ni oun ko tilẹ ronu ohun ti yoo tẹyin rẹ wa nigba ti oun ṣeranwọ fawọn Kristẹni lọjọ naa.
"Mo sọkún bíi ọmọ́dé nígbà tí à ń gbé òkú àwọn ti wọn pa sita". Imam ṣalaye bi jinijini ṣe bo gbogbo eniyan ti wọn ko roju wo ẹsin kan ni tẹnikan tabi omiran.
Bakan naa, Pasitọ atawọn Kristẹni to ku sọ ohun toju wọn ri ti wọn fi gbudọ maa dupẹ lọwọ Imam Abubakar titi di oni.