Ìkọlù Plateau: Ortom ní inú òun dùn pé Buhari ń fi àmì ẹ̀yẹ dá Abdullahi lọ́lá

Atoore ati ika, ọkan kii gbe.
Ọrọ yi se rẹgi nipa Imam ti BBC gbé ìròyìn rẹ sita lori bọ se doola ẹmi àwọn èèyàn ọ̀tàlénígba lé meji lọwọ àwọn agbebon-paniyan nipinle Plateau.
Lọ́jọ́ Ajé ni Aare Muhammadu Buhari ránṣẹ sí Imam Abubakar pé, oun fẹ ko wa bọ óun lọwọ, kí òun sì fi òye dà lọla lórí bo ti se doola ẹmi àwọn èèyàn tó sa asalà d'ọdọ rẹ, lọwọ àwọn asekupani agbebon ní àdúgbò Barkin Ladi ní ìpínlẹ̀ Plateau.
Inú mosalasi ní Abdullahi Abubakar, tó jẹ ẹni ọdún mẹtalelogun, fí àwon èèyàn naa pamọ sí lójó kẹrinlelogun osu kẹfa ọdún 2018.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Atagitá Fẹ́mi Aníkúlápó-Kútì bá obìnrin lọ l‘Amẹ́rika
- Buhari, ó yá, tètè kọ̀wé fipò sílẹ̀ - Oyedepo
- To ba n wa ọkọ̀, yàgò fáwọn ìgbésẹ̀ yìí
- Àwọn ọmọ Iyabọ Ojo rí Bàbá lẹ́yìn ọdún mẹ́fà
- Pásítọ̀ àti Ìmàámù yóò gba owó osù lọ́wọ́ ìjọba
- Ìmáàmù yiì dóólà ẹ̀mí 262 Krìstìẹ́nì ni Plateau
- Àwòrán ìkọlù Plateau tí ọ̀pọ̀ ẹ̀mí ti sùn
- Ìgbà wo ni Buhari yóò simi àwáwí?
Àwọn tí Abubakar doola ẹmi wọn sọ fún BBC pé, inú àwọn dùn gán bi Aare ṣe fẹ dá Abdullahi lọla.
Wọn ní bí ki ba se pe o gbe ìgbésẹ tó gbé, àwọn ki bá má wa l'ayé lóni.
Ewé, aṣojú ilé Amerika sí orílèèdè Naijirià náà ti gba lalejo.
Oju wo ni Gomina Ortom fi wo igbesẹ yii ?
Gómìnà ipinle Plateau Simon Lalong, lo fi ikede si'ta pé Ààrẹ Buhari fe fojú kan Abdullahi, níbi àpérò kan tí yóò wáyé lórí ètò alafia ati aabo.
Gómìnà Lalong ni, gbogbo ìlú ní Abdullahi dóóla ẹmi wọn pẹlú èèyàn oodunrun tí o gbà lá.
Yakubu Datti, to je agbẹnusọ fún Gómìnà Lalong ní, àìsí nílé Ààrẹ Buhari lo faa, ti àwọn kò ti le fi sọ àsìkò àti ààyè ti idanilọla náà yóò to wáyé.
Gómìnà Lalong ní, ayọ òun kún pe àsìkò ti òun jẹ Gómìnà ni irú nnkán bayii wáyé.














