Omoyele Sowore: Sowore gbòmìnira láhàmọ́ọ́ DSS pẹ̀lú ọgọ́rùn ún mílíọ̀nù náírà

Omoyele Sowore

Oríṣun àwòrán, Instagram/Sahara Reporters

Lẹyin ọ rẹyin, ileẹjọ giga ti ijọba apapọ l'Abuja ti gba beeli Omoyele Sowore to ṣagbatẹru iwọde #RevolutionNow.

Ọgọrun un miliọnu nairia ni ileẹjọ fi fun Sowore ni beeli pẹlu oniduro meji lọsan ọjọ Ẹti.

Sowore ti wa ni ahamọ ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ DSS lati ọjọ kẹta oṣu Kẹjọ ọdun yii lẹyin ti wọn mu un niluu Eko.

Adajọ Ijeoma Ojukwu paṣẹ fun Sowore pe ko gbọdọ rinrin ajo kuro l'Abuja.

Ẹwẹ ileẹjọ kan ti kọkọ paṣẹ pe ki ajọ DSS fi Sowore silẹ latimọle wọn pẹlu akẹgbẹ rẹ, Olawale Bakare, ṣugbọn ajọ DSS kọ lati tẹle aṣẹ ileẹjọ.

Aadọta miliọnu naira ni ileẹjọ fi gba beeli Bakare lẹyin ti wọn fi ẹsun onikoko meje kan wọn ninu eyi ti ifipa doju ijọba bolẹ wa ninu rẹ.

Adajọ Ojukwu ni kosi idi kan to le mu ki ileẹjọ ma fun Sowore ati Bakare ni beeli.

Ṣugbọn adajọ kilọ fun Sowore pe ko gbọdọ ba awọn akọroyin sọrọ lẹyin beeli rẹ.