Rochas Okorocha: Pẹ̀lú ọrọ̀ ajé wa yìí, a kò nílò aṣòfin púpọ

Oríṣun àwòrán, @realRochas
Laipẹ yii ni gomina ana ni Ipinlẹ Imo ti o tun jẹ ọmọ ile Igbimọ Aṣofin Agba, Rochas Okorocha ti bẹnu atẹ lu ifowoṣofo lori awọn Aṣofin.
Ẹwẹ, BBC Yoruba kan si agbẹjoro to jẹ onimọ nipa ofin ilẹ Naijiria.
Nigba ti akọroyin n beere boya iru aba yii dara, Agbẹjọro Deji Ọlanbiwọninu ṣalaye pe, awọn aṣofin wa ko ni gba ki iru aba bẹẹ mulẹ.
Ninu ọrọ Agbẹjọro naa, o ni owo ti ijọba n na lori awọn Aṣofin naa ko kere rara.
Ọlanbiwọnninu wa ni ṣiṣe amulo aba naa yoo gba ọpọlọpọ akoko ṣugbọn yoo ṣe orilẹede yii ni anfaani to pọ ti wọn ba le gunle ṣiṣe adinku ọhun.
Okorocha ti o n ṣoju Iwọ Oorun Ipinlẹ naa daba pe ki wọn ṣe adinku si iye Aṣofin to n ti Ipinlẹ kọọkan jade.
O tẹsiwaju pe eyi yoo mu adinku ba iye owo ti Ijọba apapọ n na lori ikọọkan awọn Aṣofin naa.
Aba ti o mu wa yii jẹyọ nigba ti o n dasi ọrọ lgbimọ ti o n ri si eto lṣuna ati Alakalẹ.
O fidi rẹ lelẹ pe, ṣiṣe adinku ba awọn Aṣofin yoo ṣe iranlọwọ pupọ ninu eto inawo ti o si jẹ ọna ti o dara ju fun orilẹ ede.
Okorocha ni ti wọn ba le gunle iru amọran bẹẹ , yoo mu amuye to peye ba eto inawo ni orilẹede yii.
O ni asiko ti to fun orilẹede yii lati pe ajọ toni ironu piwada ki a si ni amojukuro lori awọn amuyẹ kan.
Sẹnatọ naa ni lootọ ni ofin ilẹ yii fi aaye silẹ fun sẹnatọ mẹta lati ipinlẹ kan sugbọn to jẹ wi pe ẹnikan le ṣe iṣẹ sẹnstọ mẹta..
O tun ni ohun ti Orilẹ ede yii nilo lọwọlọwọ yii lati nawo si imu gbooro eto ọrọ aje nitori idokowo ni eto iṣejọba.
Kete lẹyin ọrọ naa ni Aarẹ ile igbimọ Aṣofin agba,Ahmed Lawan ti ni ki Okorocha ki o ti aba naa lẹyin de gbogbo ibi to ba ye lati mu ero rẹ ṣẹ.













