BBC World: Iléeṣẹ́ BBC fi ètò tuntun lọ́lẹ̀ fún àwọn àkàndá

Tony Hall to jẹ ọga agba patapata fun ileeṣẹ BBC ni gbogbo agbaye ti kede eto tuntun kan ti yoo ṣe awọn akanda ẹda ni anfani.
Eto naa to pe akọle rẹ ni "Aim High" lo fi lọlẹ lẹyin awọn idanilẹkọọ to waye nigba to ṣabẹwo si ẹka ileeṣẹ naa to wa lorilẹ-ede Kenya.
Hall sọ pe, eto naa yoo fi aye silẹ fun awọn akoroyin mẹta to jẹ akanda lati ṣiṣẹ fun oṣu mẹta, bẹrẹ lati ọsun kẹrin ọdun 2020.
Awọn akọroyin naa yoo siṣẹ lori ẹrọ asọrọmagbesi ati ẹrọ ayelujara ni ẹka ileesẹ BBC to wa ni Nairobi, pẹlu awọn akẹgbẹ wọn miran lati orilẹ-ede Afirika.

Hall ni "Iroyin BBC to n wa lati ilẹ Afirika n de ọdọ awọn eeyan ti ko din ni ọgọrun un miliọnu kan."
O tẹsiwaju pe "A fẹ ki awọn akọroyin ṣe iṣẹ wọn lai si ibẹru, a si fẹ ran awọn alaabọ ara lọwọ."
Hall ni oun mọ pe o ṣoro fun awọn akanda ẹda lati gbori soke ninu isẹ akọroyin.
O sọ siwaju sii pe "Afojusun wa ni lati pese idanilẹkọ to peye fun wọn, mo si rọ awọn ti ọrọ naa kan lati mu anfani yii ni ọkunkundun."
Alaye ni kikun nipa eto naa ni ileeṣẹ BBC yoo fi lede ti asiko ba to.













