Xenophobic Attack: Báwo ni ìkọlù sáwọn àjèjì ṣe pọ̀ tó ní South Africa?

Aarẹ Muhammadu Buhari bẹrẹ irinajo abẹwo si orilẹ-ede South Africa lọsẹ yii lati ṣatunṣe to yẹ ninu ajọṣepọ orilẹ-ede mejeeji.
Abẹwo yii n waye lẹyin ikọlu sawọn ajeji to ṣẹlẹ ni Soth Africa laipẹ yii ni eyi ti ọpọ awọn ọmọ Naijiria ti ni lati pada wa sile.
Opo ẹmi ati dukkia lo sọnu ninu ikọlu naa.
Igbagbọ awọn eniyan Naijiria ni pe ki Aarẹ Buhari sọrọ yanju pẹlu Aarẹ ilẹ South Africa lori bi awọn to ku a ṣe maa gbe ni alaafia.
Ibeere nla ni pe igba melo ni ikọlu sawọn ajeji ti waye ni South Africa?
Ijọba Orilẹ-ede South Africa ko ri akọsilẹ kankan fi sita lori odiwọn iye igba ti ikọlu ti waye ni South Africa sawọn ajoji.
Sugbọn African Centre for Migration and Society (ACMS) to jẹ ajọ to n risi igbokegbodo awọn eniyan Adulawọ ni akọsilẹ nipa iṣẹlẹ ikọlu sawọn alejo ni South Africa.
Lati ọdun 1994 ni wọn ti n lo Xenowatch tracker to n ṣe akosile awọn iroyin ikọlu to n jade ati awọn ti ikọlu naa ṣẹlẹ si ni igba kọọkan.
Akosilẹ ikọlu si ẹmi ati dukia awọn alejo ni South Africa:

Akọsilẹ yii fihan pe tọdun 2008 lo peleke julọ si awọn aṣatipo ati alejo to n gbe ni South Africa.
Iwadii lori ikọlu awọn ọdun kọọkan:
Lọdun 2015 ni wọn kọkọ bẹrẹ ikọlu ni Durban ati Johanesburg ni eyi tijọba ni lati fawọn ọmọ ogun ranṣẹ lo daabo bo awọn eniyan agbegbe yii.
Loṣu kẹta nijoba bere igbesẹ lati yi ero awọn eniyan pada lori kikoni mọra lai maa dẹyẹsi alejo.
Awọn ajajngbara ni igbesẹ ijoba yii dara ṣugbọn wọn nilo lati gba pe awọn eniyan South Africa n ṣe ikọlu ti ko yẹ sawọn ajoji.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Egbẹ oṣelu alatako ni South Africa, Democratic Alliance loṣu kẹwaa, ọdun 2018 di ẹbi iṣẹlẹ yii ru ijọba to n tukọ South Africa nigba naa.
Wọn ni ẹgbẹ ANC lọwọ ninu ikọle awọn ajoji.
Nibo ni awọn ajoji ilẹ South Africa ti wa?
Awọn orilẹ-ede to sunmọ South Africa ni awọn alejo to wa ni South Africa ti wa iṣẹ aje wa.
Awọn eniyan wa lati Zimbabwe, Mozambique, Lesotho to to ida aadọrin ninu ọgọrun un awọn ajoji.
Ida ọgbọn to ku wa lati Malawi, UK, Namibia, eSwatini, ti a mọ si Swaziland tẹlẹ, India atawọn ibo miran.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bawo ni gbogbo wọn ṣe pade?
Ẹkun Gauteng lo tobi ju, nibẹ naa ni Johanesburg to jẹ ilu to tobi ju ni south Africa naa wa.
Oretoria to jẹ olu ilu South Africa naa wa nibẹ ni eyi to fi jẹ pe ẹkun yii ni ikọlu ti wọpọ si julọ.
Ekun Western Cape ati KwaZulu-Natal nibi ti Durban wa naa lo tun tẹlẹ (ACSM).
Awọn ija abẹle bii ede aiyede pẹlu awọn alejo ni eyi ti wọn ni awọn alejo n gba iṣẹ awọn ṣe.

O le ni ida mẹtdinlọgbọn ninu ogorun un awọn eniyan ti wọn padanu iṣẹ oojọ wọn.
Eto ọrọ aje Souh Africa ti n lọ silẹ sii.
Orilẹ-ede yii lo ni akọsilẹ iṣekupaniyan to pọju ni gbogbo agbaye.
Airiṣẹṣe, ìṣẹ́ ati òṣì naa wa ninu nkan to n ṣokunfa ikọlu sawọn ajeji gẹgẹ bi Sharon Ekamaram to n ṣamojuto ọrọ awọn aṣatipo se sọ.
O ni South Africa ko ri iṣẹ pupọ pese mọ fawọn eniyan ni eyi to hande ninu eto ijajangbara fawọn agbejọro to n mojuto pẹlu.
















