Xenophobia: South Africa bẹ Naijiria lórí ìsekúpani nítorí ẹ̀yà!

South Africa

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, South Africa kò le kó iyán Naijiria kéré nípa ìrànlọwó àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ tí wọn n rí lò láti Naijiria.

Aarẹ orilẹede South Africa, Cyril Ramophosa ti tọrọ afọriji lọwọ awọn ọmọ orilẹede Naijiria lori isekupani awọn ọmọ Naijiria to wa ni South Africa.

Awọn Asoju orilẹede Ilẹ South Africa lo tọrọ aforijin naa ni ilu Abuja.

Aarẹ Ramophosa naa ni ọrọ itiju gba a ni isẹlẹ naa, ti o si ran awọn asoju naa lọ si orilẹede meje ti wọn faragba ninu isẹlẹ naa.

Àkọlé fídíò, Xenophobia: Naijiria á kọ́kọ́ pèsè ọ̀nà láti bá ẹbí sọ̀rọ̀ fún wọn

Ọpọlọpọ awọn eniyan lo ti bu ẹnu atẹ lu igbese awọn ọmọ ilẹ South Africa to n pa awọn alawọ dudu pẹlu ẹsun pe, wọn ko jẹ ki awọn ri isẹ se.

Àkọlé fídíò, Olutoye: Ọmọ ọdọ̀ àgbà ni mí, kò sì y kí èdè Yorùbá parun

Eniyan mejila lo ku ninu isẹlẹ naa, ti mẹwaa si jẹ ọmọ orilẹede South Africa.