Xenophobia: Buhari pàṣẹ pé kí wọ́n kó àwọn ọmọ Nàìjíríà kúrò ní South Africa

Oríṣun àwòrán, @MBuhari
Aarẹ Muhammadu Buhari ti paṣẹ ki minisita ilẹ okeere, Geoffrey Onyeama, ri pe ijọba South Africa gbe igbesẹ lati pana ikọlu ṣiṣe si awọn ọmọ Naijiria lorilẹede naa.
Buhari paṣẹ yii lẹyin ti ikọ to ran si South Africa, Ahmed Rufai Abubakar n jabọ irinajo rẹ si orilẹ-ede naa nile ijọba l'Abuja.
Bakanna ni o ni ki awọn ọmọ Naijiria ti o ba ṣetan lati pada wale kuro lorilẹede naa wa si Naijiria ni kiakia.
Aare Buhari lo ran ikọ rẹ naa lọ si South Africa, lẹyin ti iroyin jade lori ikọlu ti awọn eeyan ilẹ naa n ṣẹ si awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria to n ibẹ.
Ijọba Naijiria wa n bere owo gba mabinu lọwọ South Africa ati pe ki ajọ ọlọpaa Naijiria pawọpọ pẹlu awọn ojugba wọn ni orilede ọhun.
Lara awọn ohun ti aṣoju aare Buhari jẹ niṣẹ fun aare Cyril Ramaphosa ti South Africa ni ikorooju ijọba orilẹede Naijiria ṣe bu ẹnu atẹ lu awọn ikọlu to n waye si awọn ọmọ orilẹ-ede yi lera lera.

Oríṣun àwòrán, @MBuahri
Ati pe ijọba Naijiria ti setan lati fọwọsowọpọ pẹlu South Africa lati foju awọn ọmọ orilẹede yi wina ofin.
Aarẹ Ramaphosa ni ikọlu naa jẹ ohun idojuti nla fun orilẹede oun, ati pe oun ṣetan lati fọwọsowọpọ pẹlu Naijiria lati daabo bo awọn orilẹede yi to n gbe ibẹ.












