Nigeria governor's Forum: Kò sí Móṣáláṣí lórí ilẹ̀ náà, kòròfo ilẹ̀ lásán ni

Oríṣun àwòrán, @others
Lori ọrọ Gomina Wike ati Mọṣalaṣi ti wọn ni o wo ni ipinlẹ Rivers ni ootọ ọrọ ti n fojuhan.
Gomina ipinlẹ Rivers, Nyeson Wike ti ṣalaye wi pe oun ko wo Mọṣalasi rara tako awuyewuye ọrọ to n lọ lori ayelujara pe oun ṣe bẹẹ.
Wike lo sọrọ yii nigba ti o n mu alaga ajọ awọn gomina, Kayode Fayemi rin lori ilẹ ti wọn ni o ti wo mọṣalaṣi naa.Wike kìí ṣe dọ́là tí Ganduje leè kó sápò- Agbẹ́nuso ìjọba ìpínlẹ Rivers
- Ìfẹ̀hónúhàn l'Abuja lórí ìdájọ́ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó gbẹ́sẹ̀ lé $9.6bn ohun ìní Nàìjíríà
- A fẹ́ bẹ̀rẹ̀ òfin má lo fóònù mọ́ fàwọn ọmọ wa -Òbí
- Ìṣẹ̀lẹ̀ Bakana: àwọn tórí kó yọ fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ètò ìrànlọ́wọ́
- Gómìnà ìpínlẹ̀ Rivers, Wike pàṣẹ kí agbófinró mú kọngílá ilé tó wó ní Portharcourt
- Ọọni pe fun ifọwọsowọpọ Naijiria

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Gomina Wike salaye fun gbogbo awọn to kọwọrin pẹlu alaga ajọ awọn gomina ni Naijiria pe ko si ile tabi Mọṣalaṣi lori ilẹ naa lasiko to n mu Fayẹmi rin kaakiri ilẹ naa.
Ninu atejade kan ti abẹnugọ awọn gomina, Abdulrazaq Barkindo fi sita lọjọ Isinmi ọsẹ yii, O ni pe ko si ohun to jọ bẹẹ rara.
Fayemi to jẹ gomina ipinlẹ Ekiti salaye pe ko si ohun to dara bii ki a ri aridaju ọrọ ki a to maa fi iru ahesọ bee sita.
Wike wa fi idunnu rẹ si ipa pataki ti Fayẹmi ko lojuna ati pana ahesọ ọrọ naa ni pataki laarin awọn Musulumi ipinlẹ naa.
Igbimọ ajọ awọn gomina ti Fayemi soju wa rọ awọn Musulumi lati kọ eti ikun si ọrọ naa pe Wike wo Mọṣalaṣi ni ilu Port Harcourt.
Fayemi salaye pe panti lasan ni won n da si ori ilẹ naa ti ko si si aridaju pe ohunkohun bii ile wa lori ilẹ ọhun ri.
O ni o yẹ ki awọn eeyan maa ṣe iwadii ni kikun lori ọrọ ki wọn to bẹrẹ ahesọ to le da ẹbi, ilu tabi ipinlẹ ru bi eyi ti wọn n sọ lori Mọsalaṣi naa, eyi to jẹ irọ funfun balau.













