AEDC: Ìdí rèé ti Nàìjíríà fí ń gbé inú òkùnkùn

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọpọ lo ro pe dida ájọ ìná mọ̀nàmọ́na gẹ́gẹ́ bi wọ́n se ti n ṣe láti ọdún díẹ̀ sẹ́yìn yẹ ko fopin si airina ọba lo ni Naijiria.
Bí ó ti lẹ̀ jọ́ pé orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ta iná mọ̀nànmanà fún aládaní lójùnà ati mú ki ètó amúsagbára rú gọ́gọ́ síi, síbẹ̀ àwọn ọmọ Naijíríà ṣi ń kigbe àìrínà lò.
Usman Mohammed tó jẹ alága ilé iṣẹ to ń pin ina mọnàmọná sí ilé tó n fún ojúle kọ̀ọ̀kan ni ina mọnàmọ̀nà (TCN), jẹ́ ọkàn nínú àwón tó n ké gbàjàre pé ki ìjọba gbé igbésẹ ti yóò so eso rere láti wá ojúutu si isòrò airina lò náà to sọ orílẹ̀-èdè yiìí sínú òkùnkun.
Usman ní : "O yẹ ki ìjọba pàsẹ fún àwọn tó n ṣòwò iná mọ̀nàmọ́nà láti fi kún owó ti wọn fi n ṣòwò lójùnà àti wọn le ṣe àtunṣe si àwọn ẹka ti kò jẹ́ ki iṣẹ́ wọ́n yọ"
"Sùgbọ́n tí èyí bá lọ o túmọ si pé gbogbo àwọn to kù yóò bàjẹ́, kò sì ni sí ọ̀nà abáyọ fún àtunṣe, nitori náà a o maa wa nínú ìṣòrò nigbogbò ìgbà"
Àwọn onímọ ní ìsòrò ìna ti a ni Naijiria kò sẹ̀yìn ọ̀nà bí awọn ilé ìṣẹ́ to wà nidi ọ̀rọ iǹá ṣe ń se ipòlowó wọ́n láti mú àwọn ènìyàn dókoowò ìná mọ̀námọ́nà àti pínpín rẹ̀.
O ní àwọn míràn rò pé ìdásílẹ̀ DISCO ní ọ̀nà abáyọ sí ibi ti wọ́n maa dájọ ìná mọ̀nàmọ́na sí gẹ́gẹ́ bi wọ́n se ti n ṣe láti ọdún díẹ̀ sẹ́yìn.
Àwọn ilé iṣẹ́ towà ni ẹ̀ka tó n pin iná mọ̀nàmọ́nà pọ̀ ní orilẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Ìsòrò àìríná lò jẹ́ ọ̀kan pàtàkì ni orílẹ̀ yìí, èyí sí nń pa àwọn ilé iṣẹ́ míràn to yẹ kí o ti mú ìdàgbàsoke ba orílẹ̀-èdè yiìí.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Níńu oṣù keje ijọba Naijiria ati Siemens to jẹ ilé iṣẹ̀ Germany jọ kọwọ́ bọ̀wé adehun fún ina mọ̀námọnà.
Gẹ́gẹ́ bi ààrẹ Muhammadu Buhari ṣe sọ àjọsepọ náà yóò pèsè ìná mẹ́gà-wáàtì ẹgbẹ́run meje ní ọdun 2021 ti yóò si goke dé ẹgbẹ̀run mọkànlá ni ọdún 2023.













