Lagos-Ibadan Repair: Àwọn ọ̀ná míràn ti e lè gba jáde tàbi wolé si ìpínlẹ̀ Eko

Lagos Ibadan

Oríṣun àwòrán, LASMA

Àkọlé àwòrán, Àtúnṣe òpópónà Lagos-Ibadan àwọn ọ̀ná míràn ti e lè gba

A ti ṣetan lati tun opopona marosẹ Eko si Ibadan ṣe ṣaaju ọdun.

Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn ṣe jáde pé apá kan òpópónà márosẹ̀ Lagos-Ibadan yóò di títì pá kí ọdún kérésìmesì, ọ̀pọ̀ ènìyàn tó ń ṣe àmúlò ọ̀nà náà ló si ti ń ke gbàjare pe súnkẹrẹ fakẹrẹ ojú pópó náà kò ṣe fẹnu sọ.

Ilé iṣẹ́ to n ri sí ìgbokegbodo ọkọ̀ ni ìpínlẹ̀ Ogun (TRACE) tí gba àwọn awakọ àti gbogbo àwọn tó n sàmúlò ojú pópó náà láti lo àwọn ọ̀nà yìí.

Babatunde Akinbiyi to jẹ́ agbenusọ ilé iṣẹ́ náà sàlàyé pé nítori àtunṣe to n ṣẹlẹ̀ ní ìhà Berger -Ogun River kí awọn awakọ rin òpópónà Ìyànà ìpájà/ Ota/Abeokuta/Sagamu-Benin Ore.

Bákan náà ní wọ́n tun le gba òpópónà Victoria Island/Lekki/Epe/Ijebu-Ode-Benin/Ore.

Akole Lasma

Oríṣun àwòrán, LASMA

Àkọlé àwòrán, Lagos-Ibadan Repair: Àwọn ọ̀ná míràn ti e lè gba jáde tàbi wolé si ìpínlẹ̀ Eko

Tàbi Ikorodu/ Itoikin/ Ijebu-Ode-Benin/Ore

Akínbiyi ni àtunṣe òpópónà oní kìlómítà ẹgbẹ̀ta náà yóò wáye láti ọjọ́ keji, oṣù kẹsàn an sí ọjọ́ kẹẹ̀dógun, oṣù kejila, ọdún 2019.

Bakan naa náà lo rọ gbogbo àwọn arinrinajo láti ṣeto ìrìn wọ́n ki wọ́n tó gun le.