African Games: Àwọn akọni Nàìjíríà padà sílé pẹ̀lú àmì ẹ̀yẹ 121 láti Morocco

ola

Oríṣun àwòrán, @others

Àkọlé àwòrán, Olajide Omotayo, ọkan lara awọn akóni to gbogo fun Naijiria ni Morocco

Awọn akọni to lọ ṣoju Naijiria ninu idije African Games ti orilẹ-ede Morocco gbalejo ẹ ti de pada sile pẹlu ariwa ayọ.

Ilu Abuja to jẹ olu ilu Naijiria ni wọn kọkọ fabọ sí lalẹ ọjọ Aiku.

Ipo keji lapapọ ni wọn gbe ninu ẹlẹekejila idije ilẹ Adulawọ ọhun ni Rabat ni Morocco.

Ọgbẹni Sunday Dare, minista fun ọrọ awọn ọdọ ati ere idaraya atawọn eekan mii nijọba lo wa ni papakọ ofurufu Nnamdi Azikwe lati ki wọn kaabọ sile.

Minista ere idaraya gboriyin fun awọn akọni yii fun gbigbe ogo Naijiria ga ni Morocco.

O ṣeleri fun wọn pe oun maa mojuto ipese igbeaye irọrun sii fun wọn lasiko yii paapaa lasiko igbaradi de idije.

Orilẹ-ede Egypt to gba idije naa kẹyin naa lo tun bori ni tọdun yii ni eyi ti Naijiria ti gbe ipo keji lapapọ.

Egypt ni goolu mọkandinlọgọrun, fadaka mẹrindinlọgọrun ati baba mọkandinlaadọrin nigba ti Naijiria ni apapọ mọkanlelọgọfa.

South Africa, Algeria ati Morocco to gbalejo idije naa ni wọn jọ fi jẹ marun un loke tente atẹ idije tọdun yii.

Ọjọ kọkandinlogun si ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kẹjọ ni idije naa waye.

Orilẹ-ede Ghana lo maa gbalejo ti ọdun 2023.