AFCON 2019: Àwọn orílẹ̀èdè tó ń ṣe bẹbẹ nínú ìdíje tó ń lọ ni Egypt

Asia AfCON
Àkọlé àwòrán, Nínú àwọn olrílẹ̀-èdè yìí, orílẹ̀-èdè bíi Burundi ti Nàìjíríà kọ́kọ́ bá gbá, Mauritanian àti Madagascar ń kópà fún ninu ìdíje AFCON fún ìgbà àkọ́kọ́.

Òní ní ó pé ọjọ mẹ́jọ tí ìdíje AFCON ẹlẹ́ẹ̀kẹtàlá irú rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Egypt. Ìdíje tó bẹ́rẹ̀ ni ọjọ́ kọkànlélógun oṣù kẹfa ọdún yìí ní bi ti àwọn orílẹ̀-èdè Afíríkà mẹ́rìnlélógun tí ń fi igagbága.

Nínú àwọn orílẹ̀-èdè yìí, bíi Burundi ti Nàìjíríà kọ́kọ́ bá gbá, Mauritanian àti Madagascar ń kópà ninu ìdíje AFCON fún ìgbà àkọ́kọ́.

Àkọlé fídíò, Kayefi BBC Yorùba: Bàbá ọmọ, Mọ́ṣúárì, Ọlọ́pàá kẹ́jọ́ rò nípa òkú ọmọ tó pòórá

Awọn orílẹ̀-èdè to jáde wá náà ni Algeria, Angola, Burundi, Benin, Cameroon, Democratic Republic of Congo, Eygpt, Ghana, Guinea, Guinea Bissau, Ivory Coast, Kenya, Madagascar, Mali, Mauritania, Morocco, Namibia, Nigeria, Senegal, South Africa, Tanzania, Tunisia, Uganda ati Zimbabwe.

Níbayìí orílẹ̀-èdè mẹ́ta ló tí wọ ipele ẹlẹ̀ni mẹ́rìndínlógun, tí Nàìjíríà sì jẹ́ orílẹ̀-èdè àkọ́kọ́ to kọ́kọ́ pegedé, Egypt àti Algeria pẹ̀lú ojú àmì mẹ́fà.

Lónìí, ìdíjé náà ń tẹ̀síwájú láti tún mọ orílẹ̀-èdè mẹ́jì tí yóò kú. Àwọn mẹ́ta tó ti pegede fún ipele ẹlẹ́ni mẹ́rìndínlógun Morocco àti Ivory Coast yoo gbẹ́na wóju ara wọ́n ní ààgo mẹ́fà ìrọ̀lẹ́, South Africa àti Namibia yoo figagbága ní ààgo mẹ́sàn alẹ́, nígbà ti Tunisia ati Mali náà kò ni gbẹ́yìn ni ààgo mẹ́ta ààbọ ọsán òní.