Lai, wá wi tẹnu rẹ lóri bílíọnu mẹ́jì àbọ owó DSO

Oríṣun àwòrán, @Laiofficial
Àjọ tó ń ri sí ìwà jẹ́gudujẹra ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà (ICPC) ní mínísítà fún ọ̀rọ̀ tó ń lọ àti àṣà Lai Muhammed yóò fóju han nile ẹjọ́ giga ní Abuja lati jẹ́ri lóri ẹsun síṣé bílíọnù méjì lé ọwọ́ márun tí eto igbọhun sáféfé fí sún si ẹrọ ìgbàlóde (DSO) níọ̀n[s ti ko yẹ.
Gẹ́gẹ́ bi àtẹjáde ti agbẹnusọ àjọ ICPC Rasheedat Okoduwa fọ́wọ́ si ṣe sọ ni pé wọn ti gbé iwé ẹ̀sùn onípele méjìlá síwaju adájọ Folashade Ogunbanjọ-Giwa tako adarí àgbà NBC Modibo Kawu, alága ilé iṣẹ̀ Pinnacle Communication, Lucky Omoluwa àti alábojutó ìgbòkègbodò ilé iṣẹ́ náà Dipo Onifade.
O fí kún un pé adarí àgbà NBC sí mínísità tẹ́lẹ̀rí lọna láti buwọlu lílo owó ìjọba láti maa sagbátẹru ilé iṣẹ́ aládanil.
ICPC ní Modibo Kawu náà kò yọ sílẹ̀ nínú awọn ti yóò foju wína òfin nítori àsìlò ipò rẹ̀.
Àjọ náà ní, ipa ti mínísítà tẹ́lẹ̀rí kó nínú rẹ̀ jẹ èyí to ń pe fún ìbéèrè lẹ́yìn ti ICPC rí lásìkò ìwádìí pé ìwé àlàsilẹ̀ láti gbé ìṣẹ́ náà jáde (DSO) bí Modibo Kawu ṣe lòó kó tọ ìlànà tó yẹ.
Ẹ̀wẹ̀ " Mohammed ti jẹ́ri sí i nínú àtẹjáde kan pé wọ́n ṣi òun lọ́na ni, gẹ́gẹ́ bi ilé ẹjọ ṣe mọ láti ẹnu ẹni to jẹri fún ICPC, Osanato Olugbemi. Gẹ́gẹ bi agbẹjọro ICPC Henry Emore ṣe sọ fún ilé ẹjọ pe sísan bílíọnu méjì le fún pinnacle gẹ́gẹ́ bii àsan-an lẹ ní kọlọfin nínú nítori pé ilé iṣẹ́ ìjọba níkan ló ni ànfani láti gba irú owó bẹ́ẹ̀''.
Ilé ẹjọ tún fi kún un pé ọ̀nà ti wọ́n gba san owó to kù náà fún ilé isẹ́ aládani tun ní kọlọfin nínú, wọ́n ní ẹ̀rí ìgbòkègbodo owó ti ko lọ ni ìlànà to yẹ tó ẹ̀ẹ̀mẹtà dín láàdọ́ta ti wọn san si awọn apo owo banki oniruuru láti ọdọ alága ilé iṣẹ Pinnacle Communications Olaoluwa ni kéte ti NBC san owo fún wọ́n.
Ẹ̀wẹ̀, àwọn ọmọ Nàìjíríà tí ń sọ̀rọ̀ lóri ìgbẹ́sẹ̀ àjọ ICPC láti gbé Lai Mohammed lo ile éjọ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1

End of X post, 2

End of X post, 3