Iléẹjọ́ Ekiti: Bàbá àti ọmọ jí igi gẹdú tó tó ₦100,000

Ilé ẹjọ́ májísírèèti kan ni Igede Ekiti ni ìpínlẹ̀ Ekiti, ti ran bàbá kan ẹni ààdọ̀rin ọdún, Adeyeye Olorunyomi àti ọmọkúnrin rẹ̀ méji, lọ si ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́fa.
Àwọn ọdaràn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta dí èrò ẹwọ́n lẹ̀yìn ti wọ́n fẹsun kan wọ́n pe, wọ́n ji igi gẹdu gbé, èyí ti owó rẹ̀ tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́run náírà.
Ọlọpàá tó wà nídi ẹjọ náà, Olubu Apata sàlàyé fún ilé ẹjọ pé, àwọn ọdaran náà tẹ ofin lóju ninú oṣù kejì ọdun 2019, ní oko Awuloju ní Igede-Ekiti èyí to lòdì sofin ipinlẹ̀ Ekiti.
O fí kún-un pé, àwọn ọdaran náà fi ìmọ̀ sọ̀kan láti ṣẹ̀ sófin lọ́na ti ó le da omi àláfíà ìlú rú, ti wọn si wọ oko tó jẹ ti Oluwadare Olowokere àti Adekunle Olowokere.
Apata ni, àwọn ọdaran náà ji igi gẹdu tó to ẹgbẹ̀rún lónà ọgọrun kan náírà to jẹ ti olufisu, bákan náà ni wọ́n ṣe ìdíwọ fún àwọn ọlọpàá mẹ́rìn kan lásiko ti wọ́n fẹ mu wọ́n.
O ni, wọ́n tun fi àdá la àwọn igi to tó méjìdínlọ́gbọ̀n ninu oko náà, èyi tó si ti mu àdinku ba iye owo to yẹ ki àwọn igi naa ta lọ́ja, bákan naa ni wọ́n sàkóba fún igi kòkó, igi obì, igi ọ̀gẹ̀dẹ̀, àti ti kókò









