Ore Helicopter: Iléeṣẹ́ ọkọ̀ òfurufú ní wọn fi ẹlikọ́pútà tó dá àríyànjiyàn sílẹ̀ dóòlà ẹmí ni

Ọkunrin kan n fi ẹrọ ilewọ rẹ ya ẹlikcputa naa ni aaring poponna
Àkọlé àwòrán, Elikoputa naa da wahala silẹ lẹyin to balẹ si aarin popo naa lati gbe eniyan kan
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ileeṣẹ ọkọ ofururu kan ti sọ fun BBC wipe, aisan to ṣadede mu ọkunrin ti ọkọ ofuruf ẹlikoputa gbe ni aarin sunkẹrẹ-gba-kẹrẹ to waye loju ọna Benin-Ore laipẹ yii.

Fidio naa to gba gbogbo ori ayelujara kan lati igba to ti jade ni ọjọ Aiku to kọja ti n fa arinyanjiyan laarin ọmọ Naijiria, ọpọ to n sọ wipe baba olowo kan ni baalu naa wa gbe nitori sunkẹrẹ-gba-kẹre ọjọ naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Fidio mu ki ọpọ bẹnu atẹ lu bi awọn olowo Naijiria ṣe n jaye alábátá.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post

Ṣugbọn ileeṣẹ to ni ẹlikoputa naa ni ko si oun to buru ninu wipe, ki awọn lọ doola ẹmi ẹni ti aisan mu ni ọna to jina.

Ọpọ lo pin fidio naa lori ayelujara ati Instagram.

Ṣugbọn Femi Adeniji, to gbẹnusọ fun ileeṣẹ Tropical Arctic Logistics sọ fun BBC wipe, oun ko mọ idi ti ọrọ naa fi fa yanpọn-yanrin.

Àkọlé fídíò, Mo máa n forin mi kìlọ̀ ìwà ìbàjẹ́ láwùjọ ni -Hameen

O ni, ki i ṣe igba akọkọ ree ti awọn baalu ileeṣẹ naa yoo rin iru irin naa. O tilẹ ni igba mẹfa ni awọn ti ṣe bẹẹ ni ọdun to kọja.

Adeniji fikun pe, ẹni ti ọkọ naa lọ gbe ni ẹjẹ ruru ni ẹru ba ba awakọ rẹ. O ṣalaye wipe, dokita kan to wa ni oju ọna nigba iṣẹlẹ naa tilẹ n ran ọkunrin naa lọwọ, ki o to di pe ẹlikoputa naa wa gbe.