Wike sí Ganduje: 'Èmi kìí ṣe dọ́là tó le kó sápò'

- Author, Karina Igonikon
- Role, BBC News Pidgin, Port Harcourt
Gómínà ìpínlẹ̀ Rivers Nyesom Wike, ní Gomina ìpínlẹ̀ Kano ń dógbọ́n láti lo ọ̀rọ̀ mọsálási tí kò ṣẹlẹ̀ láti maa dá rúkèrúdò òṣèlú sílẹ̀.
Nínú àtẹjáde kan ti agbẹnusọ rẹ̀ Simeon Nwakaudu fí síta sàlàyé pé Gómìnà Ganduje ń sọ̀rọ̀ sàkàṣàkà nípa ìpínlẹ̀ Rivers.
Ní ọjọ́ Jimọ ní ìpínlẹ̀ Kano gbe àtẹjáde kan sítà pé òun ń ró láti gbe gómìnà ìpínlẹ̀ Rivers lọ sí ilé ẹjọ́ nítori ọ̀rọ̀ mọṣálási ti wọ́n wó ni àgbègbé Trans-Amadi ní ìlú Port Harcout.
Nígbà ti BBC ló síbẹ̀ láti wo ǹkan to ṣẹ̀lẹ̀ kò rí ilé kankan ti wọ́n wó lóri ilẹ̀ náà
- Ǹkan mẹ́jọ tó máa kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀ kí olólùfẹ́ méjì tó pa ara wọn
- Owó dé! ₦30,000 owó oṣù yòó bẹ̀rẹ̀ ní September - Alága ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ l‘Ekiti
- Ọwọ́ EFCC tẹ ọ̀kan lára àwọn ti FBI fi èsún jìbìtì kàn!
- Leah Sharibu ṣì wà láàyè - Iléeṣẹ́ Aarẹ Buhari
- Ilé ẹjọ́ Kano: Ganduje kò lẹ́tọ̀ọ́ láti yan Emir
- Ganduje Video - Ìwádìí ilé aṣòfin foríṣánpọ́n
Nwakaudu nínú àtẹjáde rẹ̀ sọ pé Ganduje ò mọ̀ pé gòmìnà Wike kìí ṣe "dọ́là tí Ganduje lé kò sápò bó ṣe wùú."
Ó ń tọ́ka si fọ́nran kan tó jáde lọ́dún to kọjá níbi ti Ganduje tí ń ko dọ́la sápò, nígbà ti ti ọkunrin kan tí wọ́n pe ni kọgila tó ń ko owó fun Gbanduje.
Kò sí ẹni to ọ̀rọ̀ náà yé ìdí ti Gomina Ganduje fi karabọ ọ̀rọ̀ mọ́salási ti kìí ṣe àwọn ní wọ́n kọ́ọ

Gbọ́n misi omi o tó láàrin gómìnà alágbára méèjèjì tí wọ́n wà ni ẹgbẹ́ òṣèlú ọtọ̀ọ̀tọ yìi jẹ́ ǹkan to lè da ìjà ẹsin silẹ̀ lórilẹ̀-ède Naijiria.
Ẹsìn onigbàgbọ́ lo wọ́pọ̀ jùlọ ní ìpinlẹ̀ Rivers nígbà ti mUsulumi pọ ní ìpiínlẹ̀ Kano.

Ṣé ìjọba ìpínlẹ̀ Rivers wó mọsálásí tàbi wọ́n ò wóo?
Ńkan akọkọ to ṣe kókó ni pé kò tílẹ̀ si ilé kankan tàbi pé wọ́n ti kóle si orí rẹ̀ rí wọ́n kan n pe ni mọsálási gbogboogbo ti ó wà ni Trans-Amadi ti wọ́n si ti n fa ọ̀rọ̀ náà láti bi ọjọ́ mẹ́ta.
Ìbẹ̀ jẹ́ ibi ti àwọn musùlùmí maa n dárijọ si láti kírun, èyí lo si jẹ ki wọ́n lérò pe ilẹ̀ àwọn ní.
Imaamu àgbà mọsálásí Tran-Amadi Haroon Mohammed sọ pé láti ọdún 2007 ní àwọn ti ra ilẹ̀ náà lọ́wọ́ ọkunrin Kan.
Gómìnà àná ní ìpínlẹ̀ Rivers Chibuike Amaechi tí wó àwọn ilé o wà ni àgbègbè Rainbow ni Trans-Amadi níbi ti ilẹ̀ náà wà. Nítori pé ibẹ̀ jẹ́ àdúgbo tí wọn kọ ilé pako sí ti kò si ni ètò kankan tẹ́lẹ̀, gẹ́gẹ́ bi ijọba ṣe ni agbára lati wó ibi ti ko ba bóju mu, ìjọba fi kun nígbà náà pé àwọn ni ètò míràn fún àdúgbò náà.

Láti ìgbà náà ni àwọn Musulumi àti ijọba ti ń fa ọ̀rọ̀ náà ti wọ́n si ti wọ́ àra wọ́n ló si ile ẹjọ́.
Àwọn ìhà méèjèjì ná ló si n sọ pé àwọn làwọn jàre bọ̀ láti ilé ẹjọ́, kọ́da àwọn ìhà ti Musulumi ná[gbé àwọn ìwé kan jáde ti wọ́n fi ti ọ̀rọ̀ wọ́n lẹ́yìn pé àwọn jàre ẹjọ́ náà.
Lásìkò ti Wike náà sí orí ilẹ̀ náà, sàlàyé pé àwọn jare bọ ti àwọn Musulumi si ti pe ẹjọ́ kòtẹmilọ́rùn
Ǹkan to dáju lóri ọ̀rọ̀ náà ni pé àwọn musulumi maa n lo ill náà láti gbàdúrà , sùgbán nigba kúùgbà ti wan ba ti fi ìpill ilé lélẹ nibẹ̀, ìjọba yóò wa láti tu gbogbo rẹ̀ ká.
Di last one wey happun na on 20 August and na from dat time di tok begin say di Rivers state goment scata di Mosque.
Eyí tó ṣẹ̀lẹ̀ gbẹ̀yìn yìí lo wáye ni ogúnjọ́ oṣù kẹ́jọ ọdun yìí, àsìkò yìí ni ẹjọ́ bẹ̀rẹ̀ pé ìjọba ìpínlẹ̀ Rivers wo mọsálásí Trans-Amadi
Góminà Wike náà si ti sàlàyé pe wọ́n ti fi ofin de ilẹ náà pé wọ́n o lé kọ ǹkankan sóri rẹ̀.














