Laipẹ́, ọmọ tí kò bá pé ọdún méjìdínlógún kò ní leè jáde girama l’Ọṣun

A kan ninu kilasi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Laipẹ́, ọmọ tí kò bá pé ọdún méjìdínlógún kò ní leè jáde girama l'Ọṣun

Ọrọ eto ẹkọ awọn ọmọ jẹ wa logun -Owoẹyẹ

Olori ile aṣofin ipinlẹ Ọṣun, Timothy Owoẹyẹ ti fi to awọn eeyan leti pe laipẹ laijinna, ofin kan yoo jade ni ipinlẹ naa eleyi ti yoo kan an nipa fun awọn obi lati rii pe ọmọ wọn pe ọdun mejidinlogun ki wọn to jade ileewe girama.

Họnọrebu Owoẹyẹ ni ọpọ awọn obi ti n ti awọn ọmọ wọn ni itikuti kọja nileewe girama ju bo ṣe yẹ lọ.

Ati wi pe, ti irufẹ awọn ọmọ bẹẹ ba wa de ileewe giga tan lai tii pe ọdun mejidinlogun ti wọn yoo wa maa ba ipenija loriṣiriṣi pade nibẹ.

Bakan naa lo ni bi awọn iṣinwẹẹrẹ akẹkọọ ti ko tii mọ ọwọ ọtun yatọ si osi ṣe n jade nileewe girama bayii lai ni iṣẹ ọwọ kankan ti wọn mọ kun ara ohun ti o n kun wahala aisi iṣẹ lorilẹ-ede Naijiria.

Olori ile aṣofin ipinlẹ Ọṣun ni lẹyin ti wọn ba ṣe ofin naa, yoo wa ọwọ bi awọn ọmọ ti ko ti ja lẹnu ọmu ṣe n jade ileewe girama ni Naijiria.

O ni ipinlẹ Ọṣun kọ ni irufẹ ofin bayii yoo ti kọkọ waye, nitori naa ajọṣepọ yoo wa laarin pẹlu awọn aṣofin ipinlẹ miran lorilẹ-ede Naijiria lati rii pe awọn naa gbe iru ofin bayii kalẹ ni ipinlẹ koowa wọn.