RUGA: Adeboye ní àsìkò tó láti wá nǹkan ṣe sí ọ̀rọ̀ ètò pápá ìjẹko RUGA pátápátá

Oríṣun àwòrán, PastorEAAdeboye
Bi o tilẹ jẹ pe ijọba apapọ ni awọn ti ṣẹwe le eto idasilẹ papa ijẹko RUGA ni ọsẹ diẹ sẹyin awuyewuye lori eto naa ko dẹkun o.
Ni bayii awọn iranṣẹ Ọlọrun pẹlu ti da si ọrọ naa pẹlu ipe si aarẹ Buhari lati wọgile eto ọhun patapata.
Ọkan gboogi lara awọn iranṣẹ Ọlọrun to sọrọ bayii ni Pasitọ Enoch Adeboye ti ijọ RCCG lagbaye.
Dadi G.O. gẹgẹ bi awọn ọmọ ijọ rẹ gbogbo ṣe maa n pe e, iyẹn Pasitọ Adeboye ni: niwọn igba ti awọn eeyan ba ṣi n jẹ ẹran maalu, awọn fulani yoo ṣi maa ṣe ohun to ba wu wọn.
O sọrọ yii nibi ipade apero awọn iranṣẹ Ọlọrun gbogbo lorilẹ-ede Naijiria to waye niluu Eko.
Pasitọ agba ijọ RCCG naa sọ ọrọ rẹ bi ẹna ati owe ni eyi to jẹ lowe-lowe ni a n lu ilu ogidigbo.
O sọ itan ọrẹ rẹ kan to ni o ṣalaye fun oun ni igba kan sẹyin pe darandaran kan pa arakunrin rẹ, ẹjẹ rẹ si kan si ori koriko ti maalu jẹ, iwọ pẹlu ti kopa ninu iku arakunrin rẹ niyi lọna kan abi omiran.
Adeboye ni: "Eeyan kan o le maa pa arakunrin rẹ ki o si tun maa jẹ maalu rẹ.
Ọrẹ mi ni bi o ba gba wọn laaye lati maa da oko ni ẹyinkule rẹ bi o ba ya wọn o le ẹ kuro ninu ile rẹ pẹlu.
Ọrẹ mi ṣalaye pe bi a ba dẹkun ati maa jẹ ẹran maalu, arakunrin ti o n ta maalu naa a tun ero rẹ pa."

Oríṣun àwòrán, PastorEAAdeboye
Ninu ọrọ tirẹ nibi apero naa, aarẹ ẹgbẹ ọmọlẹyin Kristi lorilẹ-ede Naijiria, Ọmọwe Ṣupọ Ayọkunle ni bi eto aabo ṣe di eyi to n ko tẹru-tọmọ laya soke ni Naijiria yii ti di itiju nla gbaa fun awọn ọmọ Naijiria.
Ẹniọwọ Ayọkunle ni 'ki ijọba fi ofin de ẹgbẹ awọn darandaran Fulani, Miyetti Allah to n ṣe agbodegba fun awọn darandaran fulani to n gbẹmi eeyan kiri ilu."
Bakan naa lo ni ijọba gbọdọ yẹra fun ohunkohun ti o lee fa iyapa lorilẹ-ede Naijiria.












