Rape: ‘Uncle àti Granpa’ mi máa ń fi owó àti ẹ̀bùn fa ojú mi mọ́ra

Obinrin kan ninu okunkun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ọmọbinrin kan ti a fi orukọ bo ni aṣiri, ti ọjọ ori rẹ to ọdun mejilelogun bayii, ti sọ bi baba iya rẹ ṣe fipa ba lopọ fun ọpọlọpọ ọdun, lati igba to n gbe lọdọ baba naa ati iyawo rẹ, tii se iya iya ọmọ yii.

Ọmọ orukan ni ọmọbinrin naa, to jẹ ọkan lara awọn alejo wa lori eto wa taa pe ni 'Nibo laye kọju si' eyi to waye lori ikanni BBC News Yoruba lori Facebook.

Skip Facebook post

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post

Ọmọbinrin naa to wa ni ileẹkọ fasiti bayii ṣalaye wipe, ati igba ti oun ti wa ni ọmọ ọdun mẹrin ni baba iya oun naa, to jẹ eniyan kan pataki lawujọ, ti bẹrẹ si ni ba oun lo pọ.

Àwọn ìròyìn mìíràn tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ sí:

O ni nigba ti oun ba gba isinmi ni ile iwe, oun maa n lọ lo isinmi lọdọ aburo iya oun to jẹ obinrin, ki oun le farapamọ sibẹ fun igba diẹ, sugbọn kaka ki ewe agbọn dẹ, lile lo n le si fun oun nibẹ.

Ọmọge naa sọ fun BBC Yoruba lori eto naa wipe, ọkọ aburo iya oun naa tun bẹrẹ si ni fipa ba oun lopọ, gẹgẹ bi baba iya oun ti n se.

O salaye pe, baba iya oun ati ọkọ aburo iya oun, tii se ‘uncle ’ oun maa n fi owo ati ẹbun fa oun loju mọra, lẹyin ti wọn ba se ifẹkufẹ wọn tan.

Àkọlé fídíò, Rape: Oluwaseun Osowobi ní Commonwealth fún lámì ẹ̀yẹ ọ̀dọ́ tó pegedé jùlọ ní 2018

Nigba ta bi leere pe se ko si ẹnikẹni to lee fi isẹlẹ yii to leti ni, ọmọge ọhun ni oun sọ fun aburo iya oun pe ọkọ rẹ n ni ajọsepọ kotọ pẹlu oun, amọ aburo iya rẹ ni "ẹnikẹni to ba ba ọkọ mi lo pọ, yoo ku ni".

Bakan naa lo ni iya mama oun sọ pe oun ni oun n sẹju si baba iya oun, to se n fi tipa ba oun lo.

Ọmọbinrin naa wa gba awọn obinrin ti wọn ba n koju iru isẹlẹ buruku yii nimọran, lati mase dakẹ, amọ ki wọn sọ ọrọ jade, o kere tan, fun ẹnikan.

Àkọlé fídíò, COZA: Ọpọ èrò ló jáde ṣe lòdì sí ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀ Fatoyinbo

Ọmọbinrin naa ati ajafẹtọ ati amofin kan ni wọn jọ kopa lori eto wa, Nibo Laye Kọju Si naa.

Ajafẹtọ awọn obinrin, Adefunke Adewumi n tiẹ, gba awọn obinrin ati obi ni imọran wi pe, ki wọn maa ṣọra nitori wipe, iwa ifipabanilopọ laarin ile ati nita ti wọpọ bayii.

Àkọlé fídíò, CAN: Samson ni ọrọ awọn ajinigbe ti gba àpérò ní Naijiria

Bakan naa ni amofin Lawal Oyewọle ni ọwọ ofin yoo tẹ ẹnikẹni to ba n hu iru iwa buruku yii.