Community policing: Ọ̀gá ọlọ́pàá Mohammed Adamu ní ètò ń lọ fún ọlọ́pàá agbègbè

Oríṣun àwòrán, @PoliceNG
Ọga ọlọpaa patapata lorilẹede Naijiria, Mohammed Adamu ti ṣalaye pe eto ọlọpaa agbegbe yoo bẹrẹ jakejado Naijiria ni kiakia.
Bakan naa lo fi da awọn ọlọpaa loju ko si ọlọpaa ti yoo ku soju ija gbigbogun ti iwa ọdaran mọ lorilẹede Naijiria.
Ni ilu Abẹokuta ni Ọga ọlọpaa Adamu ti gbe ọrọ yii kalẹ. O ni ominu n kọ oun pe awọn ọlọpaa lọpọ yanturu lo n di oloogbe lẹnu iṣẹ a n daabo bo ilu.
- Ẹ̀tanu ni àwọn ìmáàmù Yoruba fi yan Waziri míì, ojúṣe ọba ni - Oluwo
- Gani Fawehinmi lọ àmọ́ kò kú lẹ́yìn ọdún mẹ́wàá tó dará ilẹ̀
- Ìdájọ́ ọmọ mi tó gbé àdó ìkú wọ bàálù le púpọ̀, ẹ bá mi wòó ṣe - Bàbá Mutallab
- Àtúnse gbọdọ̀ bá bí EFCC ṣe ń gbógun tí ìwà ọ̀daràn - Ọọ̀ni
- "Bàbá mi kú, kò sówó ni mo ṣe kúrò ní fásitì Ilorin láti fọ gíláàsì ọkọ̀ lójú pópó"
- Ọkọ̀ agbépo gbiná lọ́nà maròsẹ̀ Eko sí Ibadan
Bakan naa lo ṣalaye pe ijọba apapọ ti gbe atunto eto igbayegbadun jade fun awọn ọlọpaa paapaa lori itọju ilera wọn ati lati lee ni ilera ara wọn.
O ni ijọba n gbiyanju gẹgẹ bii ara ọna lati din alaafo to wa laarin ọlọpaa ati araalu ku, lati rii pe araalu gan lo n ṣeto akoso abo agbegbe wọn ti awọn ọlọpaa yoo si fun wọn ni atilẹyin gbogbo to ba yẹ.
o fi kun pe awọn ọlọpaa ti wọn yoo gba fun amojuto agbegbe kọskan yoo jẹ awọn ti a bi ni irufẹ agbegbe bẹẹ ki wọn lee daabo bo wọn bi o ti tọ.








