South Africa killings: Ìjọba àpapọ̀ ní kò sóun tó jọ ìbúgbàmù àdó olóró níléeṣẹ́ ìjọba South Africa tó wà nílùú Abuja

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iroyin kan gba ori itakun ayelujara pe awọn leṣebi-leṣeka ẹda kan ti ju ado oloro si olu ileeṣẹ ijọba orilẹede SouthAfrica to wa nilu Abuja.
Ko si si idi meji ti wọn so mọ ọrọ yii ju edeaiyede lori ikọlu awọn ajeji lorilẹede South Africa lọwọlọwọ.
Amọṣa, Ijọba apapọ orilẹede Naijiria ti wa bọ sigboro aye bayii lati da omi tutu si iroyin naa eyi ti wọn pe ni iroyin ẹlẹjẹ.
Ni ọjọ Satide ni minisita fun eto iroyin ati aṣa gbe atẹjade kan jade pe ko si ohun to jọ ibugbamu ado oloro ni ileeṣẹ aṣoju ijọba orilẹede South Africa ni Naijiria to wa nilu Abuja.
O ni fidio ibugbamu ado oloro ti awọn eeyan kan n gbe kiri lori itakun ayelujara kii ṣe ti ileeṣẹ aṣoju ilẹ South Africa bi ko ṣe ti ibugbamu to waye ni ibudo Emab Plaza, nitosi Banex, nilu Abuja loṣu kẹfa ọdun 2014.
Lai Mohammed to di iroyin ofege naa ru iṣẹ ọwọ awọn alatako ṣalaye pe ọgbọn ati da omi alaafia iṣejọba ru ni awọn to gbero fidio naa n da.
Alhaji Lai Mohammed wa rs awọn ọmọ orilẹede Naijiria lati maa woye gbogbo iroyin ti wọn ba n ri gba lori ayelujara nitori oye lagba n wo.








